Aisha Buhari: Ọkọ mi yóò parí gbogbo iṣẹ́ tó ti bẹ̀rẹ̀

AISHA BUHARI

Oríṣun àwòrán, @AISHABUHARI

Àkọlé àwòrán, Aare Muhammadu Buhari ló jáwá olúborí fún sáà kejì nínú ètò ìdìbò sìpò ààrẹ lórílẹ̀èdè Nàíjíríà tó wáyé ní Osù Keji, ọdún 2019.

Iyawo Aarẹ Orilẹede Naijiria, Aisha Buhari ti ni ọkọ oun yoo lo saa keji yii lati mu gbogbo ileri to ṣe lasiko ipolongo idibo lorilẹede Naijiria wa si imuṣẹ.

Aisha Buhari lasiko to n gbalejo lati ṣayẹyẹ bi ọkọ rẹ ṣe jawe olubori sọ wi pe, aarẹ yoo gbogun ti iwa ibajẹ, iṣẹ ti oṣi eleyii ti yoo mu opin ba alafo to wa laaarin awọn olowo ati awọn alaini ni awujọ.

Iyawo aarẹ naa dupẹ lọwọ awọn obinrin ati ọdọ fun atilẹyin wọn lasiko idibo naa.

Àkọlé fídíò, Jimi Agbaje: èmi kò faramó owó ẹnubodè Toll Gate Eko rárá

Bakan naa ni aarẹ Muhammadu Buhari ti wọn ṣẹṣẹ yan fun saa keji naa sọ wi pe oun mọ ipa ribiribi ti awọn obinrin ati ọdọ ko lasiko idibo naa, nitori naa oun yoo yan awọn obinrin sipo lati ba oun ṣiṣẹ.

Amọ, Aarẹ Buhari ni awọn obinrin to ni iwa ọmọluwabi to si fẹran orilẹede Naijiria ni oun yoo yan sipo.

AISHA BUHARI

Oríṣun àwòrán, @AISHABUHARI

Aarẹ naa fikun ọrọ rẹ wi pe oun yoo pese ohun ọgbin fun awọn agbẹ aroko ni iye owo ti ko kan ni leegun ẹyin, ki o ba le mu iwuri ba awọn ọdọ lati mu iṣẹ agbẹ lokunkundun.