2019 Election Update: Atiku yóò sọ̀rọ̀ lórí ìgbéṣẹ̀ rẹ̀ lórí èsì ìdìbò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Twitter/Atiku
Ajọ amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu PDP ti kede wi pe ipade pajawiri yoo waye ni oni Ọjọ Aje fun awọn ọmọ ẹgbẹ naa lori esi idibo sipo aarẹ to waye ni oṣu to kọja lorilẹede Naijiria.
Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Uche Secondus ni ẹgbẹ oṣelu ọhun yoo lo ipade naa lati fi wa atilẹyin fun oludije sipo aarẹ lorilẹede naa, Atiku Abubakar lori igbesẹ rẹ lati lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun lori esi idibo naa.
Olu ile iṣẹ wọn ni ilu Abuja ni ipade pajawiri fun naa yoo ti waye ni Ọjọ Aje, ọṣẹ yii pẹlu igboya pe niiṣe ni ẹgbẹ oṣelu APC ji ibo wọn ni idibo sipo aarẹ.
Bakan naa ni wọn yoo jiroro lori idibo sipo gomina ati ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ti yoo waye ni Ọjọ Kẹsan, Oṣu Kẹta ni ọdun 2019.









