Gbemisola Saraki: APC ló ni ìbò gomina ní Kwara ní Satide
Oríṣun àwòrán, Wikipedia
Àkọlé àwòrán, Sẹ́nétò Gbemisola Saraki tí ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí Bukola Saraki ti fi ìgbà kan sojú ẹkùn Asa/Ilorin ní ọdún 1999 àti 2003 si 2011.
Sẹnetọ Gbemisola Saraki ti ni oun yoo rii daju pe oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo gomina nipinlẹ Kwara ni yoo jawe olubori ninu idibo ọjọ kẹsan an, oṣu kẹta, ọdun 2019.
Gbemisola Saraki to jẹ ìbátan Aarẹ Ile Igbimọ Asofin, Sẹnetọ Bukola Saraki to jẹ ti ẹgbẹ oselu PDP fikun un pe AbdulRahman AbdulRasaq ni yoo fopin si saa gomina Abdulfatah Ahmed ti ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ naa.
Sẹnetọ Gbemisola Saraki ti fi igba kan jẹ́ aṣoju ẹkun Asa/Ilorin ni ọdun 1999 ko to lọ ṣe senetọ lọdun 2003 si 2011.
Àkọlé fídíò, Issa Aremu: ṣàlàyé kíkún nípa èròńgbà ẹgbẹ́ Labour to bá jáde
Ti a ko ba gbagbe, Bukola Saraki fidirẹmi ninu igbiyanju rẹ lati pada si ile igbimọ asofin agba lorilẹ-ede Naijiria ninu idibo gbogboogbo to waye ni Ọjọ Kẹtalelogun, Osu Keji, ọdun 2019.