Sunday Igboho vs DSS, AGF Malami: Agbẹjọ́rò fún Abubakar Malami ní kò sí àrídájú pé Sunday Igboho ló ni ilé tí DSS kọlù tàbí pé ẹ̀jẹ̀ èèyàn ló wà nílẹ̀ níbẹ̀ lẹ́yìn ìkọlù náà- Malami

Minisita fun eto idajọ ati amofin agba lorilẹede Naijiria, Abubakar Malami SAN ti sọ pe ko si aridaju to fi idi rẹ mulẹ pe Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho lo ni ile tawọn DSS kọlu ati pe ko si idaniloju pe ẹjẹ eeyan lawọn ẹjẹ to wa nilẹ nibẹ lẹyin ikọlu ọhun.
Ni ọjọ Iṣẹgun nibi itẹsiwaju igbẹjọ ti aṣiwaju awọn to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ n pe ni Sunday Igboho pe ileeṣẹ alaabo DSS ati minisita fun eto idajọ lorilẹede Naijiria Abubakar Malami lori bi wọn ṣe kọlu ile rẹ ti wọn si gbẹ ẹmi ati ọpọlọpọ dukia jẹ.
- Agbẹ́jọ́rò Sunday Igboho ní Benin Republic sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí Igboho fi kàn án
- IPoB yarí mọ́ Buhari lọ́wọ́, wọ́n láwọn ò fẹ́ ríi ní ìpínlẹ̀ Imo, ni wọ́n bá kéde òfin kóńlé-ó-gbélé
- Buhari, dẹ́kun àwọn gómìnà tó ń ṣe òfin tako fífi ẹran jẹko- Miyetti Allah
- Ìwà burúkú àti àìlẹ́kọ̀ọ́ ilé ló n tú ìgbéyàwó ká, kìí ṣe òògùn olóró
- Bí mo bá fún obìnrin lóyún báyìí, mi ò ní kọ oyún náà, ṣùgbọ́n… - Bobrisky
- Sunday Igboho ní ₦4m sí ₦3m ni ìkọ̀ọ̀kan amòfin mẹ́wàá ní Cotonou gbà láì dènà kí òun má lọ sẹ́wọ̀n
Agbẹjọro fun Sunday Igboho, Amofin agba Yọmi Alliyu, SAN ko fidio meji wa sile ẹjọ naa to si rọ ile ẹjọ lati wo wọn gẹgẹ bi ara awọn ẹri niwaju rẹ.
Bi o tilẹ jẹ pe agbẹjọro fun Malami tako eyi to si ni pe adajọ nikan lo yẹ ko wo fidio naa ni kọrọ ọfiisi rẹ ṣugbọn ti adajọ to n gbọ ẹjọ naa, Onidajọ Ladiran Akintọla ni ko le ri bẹl, gbangba laṣa n ta ni oun yoo fi ṣe.
Fidio bi ile Igboho ṣe ri lẹyin ikọlu ti wọn kọlu ati bi Minisita fun eto abo lorilẹede Naijiria, Bashir Magashi ṣe ke sawọn eeyan lati di ihamọra ki wọn si gba ara wọn silẹ lọwọ awọn agbebọn ni agbẹjọro fun Igboho gbe kalẹ siwaju ile ẹjọ naa.
Nigba to si fesi lori rẹ, Amofin Abubakar to n ṣoju Amofin Agba Naijiria Abubakar Malami ni ko si ohunkohun to le fi idi rẹ mulẹ pe ile Sunday Igboho ni wọn kọlu ati pe ẹjẹ eniyan lo wa nilẹ nile naa.
Ni ọjọ kini oṣu keje lawọn agbofinro DSS kọlu ile Sunday Igboho nilu Ibadan, eeyan meji lo ku nibẹ, dukia ẹgbẹlẹgbẹ naira lo si ṣofo nibẹ.
Nigba ti agbẹjọro fun DSS, Amofin T.A. Nurudeen pẹlu fi fidio meji silẹ niwaju ile ẹjọ, Ọkan lara awọn fidio naa ṣe afihan bi Sunday Igboho ṣe n sọ fun awọn eeyan pe ki awọn to n polongo ibo fun ọdun 2023 o lọ gbagbe rẹ to si tun ṣekilọ fawọn agbofinro pe ti wọn ba lepa oun wọn ko ni dele pada.













