Buhari visit to Imo: IPoB IPOB kéde òfin kóńlé-ó-gbélé, wọ́n láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

Oríṣun àwòrán, other
Ẹgbẹ ajijagbara IPOB to n pe fun idasilẹ orilẹede Biafra ti tako igbesẹ Aarẹ Muhammadu Buhari lati ṣe abẹwo sí ipinlẹ Imo lọsẹ yii. Wọn ni awọn ko fẹ ri aarẹ ni regberegbe ẹkun ila oorun gusu orilẹede Naijiria lọwọ yii.
Adari eto fún ẹgbẹ IPOB, Chika Edoziem lo kede ọrọ yii.
Ọgbẹni Chika wa pàṣẹ ofin kóńlé-ó-gbélé lati tako àbẹwò Buhari sí ipinlẹ Imo ni l'Ojobo.
- Agbẹ́jọ́rò Sunday Igboho ní Benin Republic sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀sùn tí Igboho fi kàn án
- Bí mo bá fún obìnrin lóyún báyìí, mi ò ní kọ oyún náà, ṣùgbọ́n… - Bobrisky
- Sunday Igboho ní ₦4m sí ₦3m ni ìkọ̀ọ̀kan amòfin mẹ́wàá ní Cotonou gbà láì dènà kí òun má lọ sẹ́wọ̀n
- Ìwà burúkú àti àìlẹ́kọ̀ọ́ ilé ló n tú ìgbéyàwó ká, kìí ṣe òògùn olóró
"A o fẹ Buhari nipinlẹ Imo nilẹ Biafra ni ọjọ kẹsan an oṣù kẹsan an yii.
Bakan naa ni ẹgbẹ naa tun fọnrere rẹ pe ki gbogbo awọn ọbalaye atawọn ọtọkulu ilu o jina sibi abẹwo naa paapaa eto yowu ti gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma ba gbe kalẹ nitori Aarẹ Buhari.
Gomina ipinlẹ Imo, Uzodimma ti kede èròngbà Buhari tẹlẹ lati ṣe abẹwo sí ipinlẹ naa.
Uzodimma to kede abẹwo Aarẹ Buhari si ipinlẹ naa ṣalaye pe ọkan o jọkan akanṣe iṣẹ ni aarẹ yoo ṣi lasiko abẹwo rẹ naa.








