Sunday Igboho: Agbẹ́jọ́rò Sunday Igboho ní Benin Republic ṣàlàyé pé ìfẹ́ Yoruba lòun fi n gbẹjọ́ rẹ̀ rò

Oríṣun àwòrán, others
Agbẹjọro fun Sunday Igboho, lorilẹ-ede Benin, Amofin Ibrahim Salami, tun ti fesi si awọn ẹsun ti onibaara rẹ fi kan an pe ko mojuto ọrọ oun daadaa.
Ninu ọrọ kan to tun sọ fun BBC Yoruba, Amofin Salami sọ pe "ẹni to wa ninu ọgba ẹwọn ko mọ igbiyanju ẹnikọọkan lori rẹ".
O ni ati oun, ati awọn agbẹjọro yooku n ṣiṣẹ karakara.
O fikun pe kii ṣe nitori owo ni oun ṣe n ṣiṣẹ fun Igboho. O ni iṣẹ ti oun ṣe fun wọn ju owo lọ.
"Iyawo Igboho gbe owo wa fun mi, ṣugbọn mo kọ ọ...Iṣẹ ti mo n ṣe kii ṣe nitori owo, nitori Yoruba, Oduduwa ni mo ṣe n ṣe e".
Ọgbẹni Salami fikun ọrọ rẹ pe, nigba ti ọrọ naa ba yanju, ni ki wọn o to o fun oun ni nkan ti wọn ba fẹ ẹ fun oun.
- Ṣé lóòtọ́ ni agbẹjọ́rò DSS wọ ọkọ̀ "One Chance" tàwọn adigunjalè sì jí fáìlì ẹjọ 'Igboho' lọ́wọ́ rẹ̀?
- Ẹ mú àrídájú jáde pé Igboho ló ni ilé tí DSS kọlù tàbí pé ẹ̀jẹ̀ èèyàn ló wà nílẹ̀ níbẹ̀ lẹ́yìn ìkọlù náà- Malami
- IPoB yarí mọ́ Buhari lọ́wọ́, wọ́n láwọn ò fẹ́ ríi ní ìpínlẹ̀ Imo, ni wọ́n bá kéde òfin kóńlé-ó-gbélé
- Sunday Igboho ní ₦4m sí ₦3m ni ìkọ̀ọ̀kan amòfin mẹ́wàá ní Cotonou gbà láì dènà kí òun má lọ sẹ́wọ̀n
Ṣaaju lo ti kọkọ sọ sọrọ lori fọran ohùn kan to jade si ori ayelujara laipẹ yii.
Ninu fọnran naa to tẹ BBC Yoruba lọwọ ni Sunday Igboho ti fi ẹsun kan agbẹjọro naa pe ko yọju si oun lati bi oṣu meji ti oun ti wa ni ẹwọn.
Ninu fọnran naa lo ti jọ pe Igboho n fi ẹjọ agbẹjọro naa sun ẹnikan, pe nigba ti agbẹjọro naa papa yọju si oun, niṣe lo tun n fi oun ba ẹlomiran sọrọ fun bi iṣẹju mẹẹdogun.
Eyi si lo bi Igboho ninu to fi fi ọrọ abuku ranṣẹ si awọn agbẹjọro to n ṣoju rẹ lorilẹ-ede Benin pe, wọn kii ṣe agbẹjọro daadaa.
Igboho sọ pe ṣe bi loju gbogbo wọn, ni adajọ fi paṣẹ pe ki wọn o gbe oun lọ si ọgba ẹwọn, ti wọn ko si ri ohunkohun ṣe nipa rẹ.
Bakan naa lo ni kii ṣe owo kekere ni oun san fun ẹni kọọkan wọn, amọ to ja si ofo.
- Sunday Igboho ní ₦4m sí ₦3m ni ìkọ̀ọ̀kan amòfin mẹ́wàá ní Cotonou gbà láì dènà kí òun má lọ sẹ́wọ̀n
- Ìgbẹ́jọ́ yóò tẹ̀síwájú lórí ẹjọ́ tí Sunday Igboho pe DSS àti Malami
- Kò sí aburú bí àwọn kàn ṣé n béèrè fún ìdásílẹ̀ Yorúbá Nation ṣùgbọ́n...
- Bó wù yín, ẹ gbé mi padà sí Nàíjíríà, kò sí nǹkan tí yóò ṣẹlẹ̀ - Sunday Igboho
Ṣugbọn nigba to n ba BBC sọrọ lori awọn ẹsun naa, Amofin Salami sọ pe ti ede aiyede ba tiẹ waye laarin oun ati onibaara oun, Sunday Igboho, kii ṣe inu iwe iroyin ni oun yoo ti sọ.
O ṣalaye pe awọn to gbe ohun naa jade ṣẹ si ofin orilẹ-ede Benin, fun bi wọn ṣe pin fọnran naa lai gba aṣẹ lọwọ Igboho tabi oun paapaa.
"Ẹni to tete ma n binu ni Sunday Igboho, to si le fi ibinu sọrọ, amọ n ko ni titori bẹẹ sọ ọrọ temi naa fun awọn oniroyin."
O ni Igboho ko ba ẹnikẹni ṣe ifọrọwerọ, ti oun ko si le sọ bi fọnran ohun naa ṣe jade sita sori ayelujara.
O ni oun ko ni esi fun gbogbo nkan ti wọn ni Igboho fikan oun gẹgẹ bi ẹsun. O sọ pe oun n ba iṣẹ oun lọ, bẹẹ naa si ni gbogbo awọn agbẹjọro to n gbeja Igboho wa lẹnu iṣẹ wọn.
Bakan naa lo sọ pe lootọ lo yẹ ki Igboho binu si bi wọn ṣe fi si ẹwọn ni Benin, lai jẹ pe o ṣẹ si ofin wọn.
"O yẹ ki gbogbo wa mọ pe ibinu to tọ ni ibinu Sunday Igboho."
















