Yoruba Oduduwa Nation: Ṣíṣe déédé àti ààbò tó péye láwọn Yorùbá Nation n já fún-Ooni

Oríṣun àwòrán, Yera Moses Olafare
Ooni Ile Ife Ọba Adeyeye Ogunwusi ti tun sọrọ lori igbiyanju awọn to n beere fun idasilẹ orileede Yoruba.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti Ooni ṣe pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin Naijiria, o ni awọn to n ja ija wọnyi n beere fun iṣe deede ati aabo to peye ni.
Oba Ogunwusi sọ pe ohun to daa ju ni ki Naijiria ṣe ọkan ṣugbọn ti awọn eeyan ko ba ri apẹrẹ eyi, o di dandan kawọn eeyan maa fapajanu.
Ọjaja Keji sọ pe ohun ko le da awọn to n pe fun idasilẹOduduwa Nation lẹbi nitori nkan ko ri bayi ni nkan bi ogun ọdun sẹyin.
''Nigba tawọn Yoruba wa nipo njẹ awọn eeyan fẹhonu han bayi? O gbọdọ ni idi to fi ri bayi gbogbo wa la si mọ pe wahala aisi aabo ati idigunjale lo fa''
Ori Ade naa sọ pe koda ni apa ariwa Naijiria awọn eeyan n fapajanu ati pe ohun to ṣe pataki ni ki wọn yanju awọn to n da wahala silẹ ati awọn ti o n beere nkan to lẹtọ.
''O gbọdọ ni idi ti wọn fi n sọpe awn fẹ lọ lọtọ. Imọran mi ni ki ba wọ́n jiroro. Ẹ jẹ ka jiroro lori ibaṣepọ ati isọkan Naijiria ki nkan baa le to deede''
Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa bakan naa, Ooni sọrọ nipa iṣẹlẹ to waye nibi ti Sunday Adeyemo Igboho ti tabuku rẹ.
Ooni sọ pe gẹgẹ bi baba ati ọmọ to ṣe daada ati eyi to ku diẹ kaato, gbogbo wọn loun jẹ baba fun.
O ni awọn ko ni tori ohun to ṣẹlẹ kawọn wa pa Sunday Igboho ti lai ya si rara.
Oba Adeyeye ni awọn ti ṣe agbekalẹ igbimọ lori ọrọ Igboho ki gbogbo nkan baa le lọ deede ni Naijiria ati ki wọn ba le mojuto ọrọ rẹ.
''Awọn akọṣẹmọṣẹ la ni ko mojuto ọrọ yi.A si n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn alaṣẹ lati ti pe ohun gbogbo lọ leto leto''
















