Nigeria Customs: ọgá ilééṣẹ́ aṣọ́bodè Buhari kò mọ̀ iṣẹ́ to -Sẹ́nẹ́tọ̀ Francis Fadahunsi

Oríṣun àwòrán, Facebook/customsng
Igbakeji alaga igbimọ ile aṣofin agba to n mojuto iṣẹ ajọ aṣọbode Naijiria Sẹnẹtọ Francis Fadahunsi ti ni ki ijọba wa ọna ti wọn yoo fi pawo wọlẹ lọdun 2022.
O ni eyi ṣe pataki nitori ile ko ni faramọ yiya owo lati fi ṣeto isuna.
Bẹẹ lo tun pe fun iwadii kiakia lori ina ati ilo gbogbo iṣẹ ti ileeṣẹ aṣọbode ṣe lati 2015 titi di asiko yi.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin Naijriia Punch lo ti ṣalaye ọrọ yi.
Ṣaaju ki o to darapọ mọ oṣelu, Fadahunsi ti fi igba kan jẹ igbakeji ọga agba ilẹesẹ aṣọbode Naijiria.
O ni o ṣeni laanu bi awọn ileeṣẹ to yẹ ko maa pawo wọle fun Naijiria bi ileeṣẹ aṣọbode ti ṣe kuna nidi iṣẹ wọn lati wa owo ti Naijiria yoo fi ṣeto iṣuna.
O ni yato si eleyi, ileeṣe aṣọbode ko tun ja fafa to lati koju awọn onifayawo ti eleyi si mu ki Naijiria maa padanu obitibiti owo.
Nitori naa Fadahunsi wa pe fun ikọwefiposilẹ ọga agba Customs,ọgagun fẹyinti Hameed Ali pẹlu bi ko ṣe ribi dẹkun ki ijọba maa yawo fi seto isuna.
O ni''ile aṣofin agba ko fara mọ ki Naijiria maa ya owo, ijọba apapọ ni lati wa wọrọkọ fi ṣada ''
''Gbogbo awọn olori ileeṣẹ ijọba to n pawo wọle ni lati sun ṣokoto wọn soke lati ṣiṣẹ tọ afojusun bi bẹẹ kọ wọn yoo gba iṣẹ lọwọ wọn''

Oríṣun àwòrán, Facebook/customsng
O ni ni kete tawọn ba wọle pada nile aṣofin awọn yoo daba ki ile ṣe iwadi iye kọntena ti o n wọ awọn ibudo ikẹrupamọ si.
''A o wa awọn ọga ileeṣẹ aṣọbode to ja fafa to si ti fẹyinti nidi iṣẹ ati awọn oniṣiro owo ti yoo sọ deede iye owo ti wọn n san wọle sakoto ijọba.''
Lọjọru to kọja yi ni ọga agba ileeṣẹ aṣbode sọ fun igbimọ ile to n mojuto ọrọ inawo pe awọn ko ribi pa owo wọle nitori iwa fayawọ ati awọn nkan miran.

Oríṣun àwòrán, Facebook/customsng
Fadahunsi sọ pe Hameed ko ni awijare kankan nitori ile aṣofin ti fun ni gbogbo nkan to nilo lati fi koju awọn ipenija yi.
O wa sọ pe aarẹ Buhari kuna pẹlu bo ti ṣe yan ọmọ ologun sipo ọga Customs yoo tunbọ maa kọdi erongba Naijiria lati sinmi gbese jijẹ.
O ni aṣiṣe nla gbaa ni bi aarẹ Buhari ti ṣe yan alaimọṣẹ ajagunfẹyinti sipo ọga agba ileeṣẹ aṣọbode.

















