Poverty in Nigeria: SERAP ní aráàlú ló ń jẹ ìyà torí ìwà àjẹbánu ní ẹ̀ká ìlérá, ètò ẹ̀kọ́ àti ìpèsè omi

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ajọ ajafẹtọ araalu lori ijiyin isẹ iriju ẹni SERAP) ti kede pe, ida mejidinlaadọta ọmọ Naijiria ni ko ri ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira (N100,000) bii owo to n wọle fun wọn ni odidi ọdun kan.
SERAP fi eleyii lede lasiko ti wọn n gbe iwadii jade lori ẹsun iwa ibajẹ ni ẹka eto ilẹra, ẹkọ ati omi, eleyii ti wọn ni o sọ Naijiria si oko iya ati iṣẹ.
Iwadii naa fi lede pe ọmọ Naijiria to le ni miliọnu mẹtadinlọgbọn, ni iye ti wọn n gba lọdun ko to ẹgbẹrun lọna ọgọrun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- DSS tú èèyàn méjì míì silẹ nínú àmúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho mẹ́rin tó kù sí àhámọ́ rẹ
- Yoruba Nation kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Naijiria, ìlànà àtúntò ni - Deji ti Akure
- Wo bí wọ́n ṣe le mọ́ irú èèyàn to jẹ́ àti àìsàn tó ń ṣe ọ́ látipasẹ̀ ‘Handwriting’ rẹ
- Ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram 6,000 ti jọ́wọ̀ ara wọn fún ìjọba Naijiria
- Àwọn jàndùkú tún ṣọṣẹ́ ní Zamfara, wọ́n pa ọlọ́pàá kan àti olórí fijilanté
- Á ṣiṣẹ́ tako Seyi Makinde fún sáà kejì - Igun PDP l‘Oyo fọnmú
- Wàhálà lẹ̀ ń wá tẹ́ ẹ̀ bá tú Sunday Igboho àtàwọn èèyàn rẹ̀ mẹ́rin sílẹ̀ ní àhámọ́ - Ọmọ Nàíjíríà lókè òkun
- Àìsàn wo ló ń bá Okele, òṣèré tíátà finra, tó fi dèrò ilé ìwòsàn?
- Ẹ wo àtúpalẹ̀ bí Bobrisky ṣe ná ₦500m péré láti ṣe ọjọ́ ìbí
Nigba ti ida mẹtadinlọgbọn ninu ọgọrun ọmọ Naijiria n gba owo oṣu ti ko ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun si ẹgbẹrun lọna igba naira lọ ni ọdun kan.
Bakan naa ni wọn ni ida mẹwa n gba owo to le ni ẹgbẹrun lọna igba naira si ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira ni ọdun, nigba ti ida mejila ati aabọ si n gba ju ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira lọ ni ọdun.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
''Eleyii fihan pe awọn araalu, mẹkunu lo n jẹ iya iwa ajẹbanu ni ẹka eto ilẹra, ẹkọ to fi mọ ẹka to n pese omi mimu fun awọn eniyan.''
''Ko si ipese akọsilẹ kankan ni awọn ipinlẹ to le e ṣe afihan awọn ti iya ati iṣẹ n ba finra, lọna ati ni anfaani si ipese eto ilẹra, ẹkọ ati omi mimu fun awọn eniyan.''
Ajọ ajafẹtọ araalu SERAP ni ida mọkandinlọgọrin awọn ọmọ Naijiria lo n pese omi fun ara wọn nipa gbigbe kannga tabi pipese omi ẹrọ fun ara wọn.
Bakan naa ni iwadii ọhun fikun pe ida mẹrindinlogoji ọmọ Naijiria ti iya ati iṣẹ n ba finra ni ko tun ri iwosan pipe lati ọdọ ijọba.
Ko tan si bẹ, SERAP ni awọn to tilẹ lọ ileewosan amọ ti wọn ri owo san, ni ijọba kọ lati fun ni eto ilera to peye.













