Sunday Igboho Aides: Amòfin Olajengbesi lérí láti gbé DSS lọ ilé ẹjọ́ lórí bo ṣe tàpá sí àṣẹ adajọ

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Idunnu tí subu lu ayọ fún awọn olólùfẹ́ Sunday Igboho nigba ti DSS tun tu meji silẹ ninu àmúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ mẹrin to si ku ni ahamọ.
Orúkọ àwọn eeyan meji mii ti DSS tu silẹ lọjọ Ẹti ni Tajudeen Rinloye ati Uthman Adelabu.
Àmọ́ DSS ko tu obìnrin kan ṣoṣo to wa laarin wọn ati ọkunrin miran silẹ.
Orúkọ awọn mejeeji to ku ni ahamọ ni Amudat Babatunde ti ọpọ eeyan tun n pe ni Lady K ati Jamiu Oyetunji.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram 6,000 ti jọ́wọ̀ ara wọn fún ìjọba Naijiria
- Àwọn jàndùkú tún ṣọṣẹ́ ní Zamfara, wọ́n pa ọlọ́pàá kan àti olórí fijilanté
- Á ṣiṣẹ́ tako Seyi Makinde fún sáà kejì - Igun PDP l‘Oyo fọnmú
- Wàhálà lẹ̀ ń wá tẹ́ ẹ̀ bá tú Sunday Igboho àtàwọn èèyàn rẹ̀ mẹ́rin sílẹ̀ ní àhámọ́ - Ọmọ Nàíjíríà lókè òkun
- Àìsàn wo ló ń bá Okele, òṣèré tíátà finra, tó fi dèrò ilé ìwòsàn?
- Ẹ wo àtúpalẹ̀ bí Bobrisky ṣe ná ₦500m péré láti ṣe ọjọ́ ìbí
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, agbẹjọ́rò fun awọn eeyan mejila ti DSS ko nile Sunday Igboho, amofin Pelumi Olajengbesi kede pe oun yoo pada gbé Ileesẹ agbofinro DSS rele ẹjọ.
Olajengbesi, ninu atẹjade kan to fisita wa fi ẹsun aibọwọ fún àṣẹ ilé ẹjọ́ kan àjọ DSS, to si ni eyi to ba wu, lo n tẹle ninu àṣẹ tile ẹjọ pa fun.

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore/Facebook
Olajengbesi ni DSS ko salaye idi kankan tó ṣe yari lati máṣe tu gbogbo awọn eeyan mejeejila naa silẹ ni ahamọ lasiko kannaa.
O fikùn pé gbogbo ilana ti DSS fi lélẹ̀ ni ikọ̀ agbẹ́jọ́rò naa ti tẹle lati gba idande awọn eeyan naa àmọ́ síbẹ̀ wọn kò fi eeyan meji yoku silẹ.
Bakan naa lo fikun pe DSS ko ni àṣẹ lati maa tu ẹnikẹni to ba wu silẹ tabi maa tẹle ọwọ àṣẹ ile ẹjọ to ba fẹ.
"Awawi àjọ DSS tẹ́lẹ̀ ni pe awọn agbẹjọ́rò ko pari awọn ilana to yẹ ki wọn tẹle lati tu àwọn eeyan mẹrin yoku silẹ.
Àmọ́ gbogbo ilana yii la ti parí titi ọjọ Ẹti, ọjọ́ kẹta oṣù Kẹ̀sán yii, àmọ́ ìyàlẹ́nu lo jẹ fun wa pe eeyan meji ninu mẹrin tun ni DSS fi silẹ.
Àmọ́ tí DSS ko ba tu àwọn eeyan meji to ku si ahamọ wọn silẹ títí di ọjọ Aje, ọjọ kẹfà oṣù kẹsàn-án, a pada gbe oludari agba fun àjọ DSS, Yusuf Magaji Bichi lọ sile ẹjọ lórí ẹsun titapa si àṣẹ ilé ẹjọ́."
Amofin Olajengbesi wa woye pe ko ni dara ki awọn dakẹ, ki DSS maa huwa taniyomumi nidi isẹ rẹ, ko si tun maa tapa si ofin ilẹ̀ wa.



















