Boko Haram 6,000 pẹ̀lú àwọn ẹbí wọn jọ̀wọ́ ara wọn fún ìjọba Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti kede pe nnka bii ẹgbẹrun mẹfa ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ti jọwọ ara wọn fun ijọba apapọ.
Lara awọn to jọwọ ara wọn ni awọn to jẹ ọgagun ninu ikọ naa wa, to fi mọ awọn iyawo atawọn ọmọ wọn pẹlu.
Akọroyin BBC to wa niluu Abuja jabọ pe awọn ọmọ ikọ Boko Haram kan naa to wa ni Cameroon ti jọwọ ara wọn fun ijọba orilẹ-ede ọhun.
- Àwọn jàndùkú tún ṣọṣẹ́ ní Zamfara, wọ́n pa ọlọ́pàá kan àti olórí fijilanté
- Àìsàn wo ló ń bá Okele, òṣèré tíátà finra, tó fi dèrò ilé ìwòsàn?
- Á ṣiṣẹ́ tako Seyi Makinde fún sáà kejì - Igun PDP l‘Oyo fọnmú
- Wàhálà lẹ̀ ń wá tẹ́ ẹ̀ bá tú Sunday Igboho àtàwọn èèyàn rẹ̀ mẹ́rin sílẹ̀ ní àhámọ́ - Ọmọ Nàíjíríà lókè òkun
- "Ọmọ Naijiria, ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Elédùà tó fi ìjọba Buhari ta wá lọ́rẹ''
- Ẹ wo àtúpalẹ̀ bí Bobrisky ṣe ná ₦500m péré láti ṣe ọjọ́ ìbí
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Afurasí mẹ́jọ tó tẹ ayédèrú ₦98m àti $1.5m wọ gàù àjọ DSS
Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria sọ pe ikọlu lemọ-lemọ ti awọn n ṣe si ibuba Boko Haram lapa oke ọya lo jẹ ki awọn ọmọ ikọ naa maa jọwọ ara wọn fun ijọba Naijiria.
Awọn kan to n woye bi eto abo ṣe n lọ ti ni o ṣeeṣe ko jẹ pe iku adari ikọ naa tẹlẹ, Abubakar Shekau lo jẹ ki awọn ọmọlẹyin rẹ maa jọwọ ara wọn fun ijọba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn kan lara awọn ọmọ ikọ ọhun ti ko jọwọ ara wọn ti lọ darapọ mọ apa keji ẹgbẹ naa to wa labẹ ẹgbẹ Islamic State, iyẹn, ISWAP.
Ṣugbọn ko ṣeni to ti le sọ iye awọn ọmọ ẹgbẹ naa to lọ darapọ mọ ISWAP ni pato.
Wayi o, ijọba Naijiria ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iforukọsilẹ awọn eeyan to ronupiwada naa lọna ati ṣe awọn idanilẹkọọ kan fun wọn ki wọn le yi ero inu wọn pada, ki si le darapọ mọ awọn eeyan awujọ.
Ẹwẹ, pupọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fajuro si igbesẹ ijọba lati ko awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi to ronupiwada naa pada saarin awọn araalu.
Awọn kan tilẹ n sọ pe o yẹ ki ijọba le foriji awọn eeyan bii Nnamdi Kanu ati Sunday Igboho to n ja fun ipiya to ba le forijin awọn ọmọ Boko Haram to ti fi ẹmi ọpọ ọmọ Naijiria ṣofo.
- Àwọn tó lu ₦6trn owó àjọ NDDC ní póńpó rugi oyin - Buhari fọnmú
- Kí ló dé tí Oluwo àti ìyàwó rẹ̀ àná ń sòkò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ayélujára?
- "Ojú mi rí màbo lásìkò tí mo lọ gbé N2.5m fáwọn jàndùkú tó jí ẹbí mi gbé"
- "Tí Taliban bá rí mí, ikú ní yóò gbẹyìn mi, kò sí ìdáríjìn fún mi"
- Fíìmù India tó gbé agbára oṣó àti àjẹ́ ga ló mú kí ń gbaná jẹ fún Jésù láti ṣe sinimá - Mike Bamiloye













