Buhari: Adesina ní táwọn ọmọ Naijiria bá mọ oore, ó yẹ kí wọn yin Ọlọ́run pé nǹkan ń dára si lórí ètò ààbò

Oríṣun àwòrán, Others
Oludamọran fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Femi Adesina ti sọ idi ti awọn ọmọ Naijiria fi gbọdọ dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ijọba aarẹ Buhari lori ọrọ aabo.
Adesina to sọrọ yii lori eto Channels TV ni igbagbọ oun ni pe ọpọlọpọ nnkan lo dara si, labẹ iṣejọba aarẹ Buhari.
O ni bio tilẹ jepe ọrọ aabo to mẹhẹ peleke si ni awọn ibi kan, amọ a ko si ni ibi ti a wa nigba kan ri.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ wo àtúpalẹ̀ bí Bobrisky ṣe ná ₦500m péré láti ṣe ọjọ́ ìbí mi
- Àwọn tó lu ₦6trn owó àjọ NDDC ní póńpó rugi oyin - Buhari fọnmú
- Kí ló dé tí Oluwo àti ìyàwó rẹ̀ àná ń sòkò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ayélujára?
- "Ojú mi rí màbo lásìkò tí mo lọ gbé N2.5m fáwọn jàndùkú tó jí ẹbí mi gbé"
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Ẹ se mẹ̀dọ̀ ẹ̀yin olórí Fulani, ẹ yé tàbùkù àṣà Yorùbá nílẹ̀ wa mọ́ - YCE kìlọ̀
- "Tí Taliban bá rí mí, ikú ní yóò gbẹyìn mi, kò sí ìdáríjìn fún mi"
- Omi lórí pápá ìṣeré Lekan Salami kìí ṣe tuntun, ó lè ṣẹlẹ níbikíbi - Ìjọba Oyo
- Fíìmù India tó gbé agbára oṣó àti àjẹ́ ga ló mú kí ń gbaná jẹ fún Jésù láti ṣe sinimá - Mike Bamiloye
''Ti a ba mọ oore ni, ti a si jẹ olootọ eniyan, o yẹ ki a wo awọn agbegbe kan lori ọrọ aabo, ki a si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe nkan dara si ni awọn agbegbe yii.''
''O ni awọn agbegbe kan ti nkan ti dara ju bi wọn ṣe wa tẹlẹ, bi o tilẹ jẹ pe awọn iṣoro ati idojukọ wa loriṣiriṣi''
Oludamọran fun Aarẹ Buhari lori ọrọ iroyin, Femi Adesina ni o da oun loju pe laipẹ laijina, ki ijọba aarẹ Buhari to pari, ni gbogbo idojukọ ni ẹka eto aabo yoo dopin.
Eleyii ko ṣẹyin bi awọn agbebọn ṣe ṣekọlu si ileewe awọn ọmọde ni ipinlẹ Zamfara, ti wọn si ji ọmọ to le ni aadọta gbe lọ.

Oríṣun àwòrán, Muhammed Maradun
Bakan naa ni ọpọlọpọ ijinigbe, ipaniyan ni awọn agbebọn ti ṣe si awọn ipinlẹ bii Katsina, Kebbi, Niger, Kaduna ati Zamfara, eleyii to mu ki wọn ti lara awọn ileewe ni agbegbe wọnyii.
Ni iha Guusu Naijiria bakan naa ni ijinigbe n waye, ti awọn afurasi Fulani darandaran ṣi n da wahala silẹ, to fi mọ ijinigbe ati ija pẹlu awọn agbẹ ni awọn agbegbe wọnyii.
Amọ aarẹ Buhari ninu ọrọ rẹ lasiko to n ṣe ifilọlẹ igbimọ adari tuntun fun ajọ idokoowo owoolu, NSIA, ni o di igba ti oun ba ti lọ tan ki awọn ọmọ Naijiria to lee mọ iyi oun.















