Yoruba Nation: Deji Akure ní ìrẹ́pọ̀ láàrín ẹ̀yà ní Naijiria ló le mú ìdàgbàsókè wá, kìí ṣe ìyapa

Deji ti Akure

Oríṣun àwòrán, @DailyPostNGR

Deji ti ilu Akure, Ọba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati gba ilana atunto laaye lai si iyapa ẹya kankan, paapaa ni ilẹ Yoruba.

Ọba Aladelusi lo sọ eyi ni Akure lasiko to n yan adari tuntun fun awọn ẹya Igbo ti wọn n gbe ni ilu naa.

O ni gbogbo idojukọ to n waye ni Naijiria ko ṣẹyin aigbọraẹniyẹ ati ilọgun fun iyapa ni awọn ẹkun kọọkan, to si sọ pe ọna abayọ ni ki awọn ọmọ Naijiria fi imọ ṣe ọkan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Orilẹede Naijiria ko le e ni ilọsiwaju ti awọn ẹya ba ṣi n lọgun fun iyapa kuro lorilẹede yii''

''Ẹbẹ ni ma a bẹ awọn ajijagbara fun awọn ẹkun yii lati tun ero wọn pa nitori ko le e mu idagbasoke ba orilẹede Naijiria.''

''Bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan lẹtọ si ibeere fun iṣejọba ara ẹni, wọn gbọdọ ṣe lai tapa si ofin orilẹede ni apapọ''

Àkọlé fídíò, Graphology: Wo àǹfààní márùn-ún tó wá nínú ìmọ̀ nípa ‘Handwriting’ rẹ

Deji ti ilu Akure, Ọba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi ni iṣoro to n doju kọ orilẹede Naijiria, paapaa ọrọ eto aabo ti ko muna doko, lo mu ki ọrọ aje dẹnukọlẹ.

Ọba Aladetoyinbo Aladelusi fikun pe eto aabo to dojuru naa lo mu ki awọn eniyan ma a lọgun lati kuro ni Naijiria.

Bakan naa ni Ọba alaye ọhun kesi awọn adari ati gomina lati ri pe wọn san owo oṣu awọn oṣiṣẹ nitori o pẹlu ohun to n fa ti owo Naijiria ko fi ni agbara mọ bii ti tẹlẹ.

O ni awọn eniyan gbọdọ fi imọ sọkan paapaa lori igbagbọ ati ẹsin awọn araalu lorilẹede Niajiria, ki wọn si bọwọ fun igbagbọ ara wọn.

Kabiyesi naa tun kesi awọn alejo ti wọn ba n gbe laarin awọn onilẹ lati bọwọ fun aṣẹ agbegbe naa, ki wọn si gba alaafia laaye.

Deji ti ilu Akure, Oba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi wa ṣeleri lati ri pe alaafia ati ifimọṣọkan jọba ni ẹkun oun pẹlu awọn ẹya miran to n gbe ni ilu Akure.

Àkọlé fídíò, Kayeefi: Àdììtú tó rọ̀ mọ́ ìdí tí ìlú Okeluse ṣe fi ọmọ ọdún 16, tó wà ní JSS 2 jọba