Covid-19 Vaccines: Aráàlú sọ̀rọ̀ lórí èrò ìjọba láti sọ gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára di ọ́rànyàn
Ijọba Naijiria ati awọn gomina ipinlẹ kan ti kede pe awọn yoo gbe igbesẹ lati sọ eto gbigba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 di ọranyan.
Bakan naa ni wọ̀n kede pe ẹnikẹni ti ko ba gba abẹrẹ naa yoo koju awọn ijiya kan, to si tun seese ki iru ẹni bẹẹ ma le lọ jọsin ni sọọsi tabi mọsalasi.
BBC Yoruba bọ sigboro lati mọ ero araalu nipa igbesẹ yii, ohun ti wọn sọ ree.