Sowore: Èèyàn márùn ùn láwọn tó pa àbúrò Sowore jígbé- iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe lootọ lawọn ajinigbe kan ṣeku pa aburo gbajugbaja ajafẹtọmọniyan Omoyele Sowore.

Ninu ọrọ ti a ri lọdọ ileeṣẹ iroyin Naijiria Daily Trust,alukoro awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Edo Bello Kontongs ni afurasi ajinigbe lo yinbọn pa Felix Olajide.

Bello ni lagbegbe Isuwa lopopona marose Lagos-Benin ni wọn ti yinbọn pa ni nkan bi ago meje ku diẹ lowurọ.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iwe iroyin naa ṣe sọ,awọn ọlọpaa ni wọn tun ji eeyan marun un mii gbe.

Wọn tẹsiwaju pe wọn ti gbe oku Felix lọ si aaye igbokupamọsi fasiti Igbinedion to wa ni Okada.

Ọlọpaa wa fi kun pe iwadii n tẹsiwaju lati le fi doola awọn eeyan marun un ti wọn ji gbe.

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Others

Ajafẹtọ ọmọniyan, Omọyẹle Sowore ti ṣedaro aburo re Olajide ti o pade iku ojiji ni opopona Benin-ore, ni agbegbe Okada, nipinlẹ Edo.

Ninu atẹjade ti Sowore fi si oju opo Facebook rẹ lo ti kerora iku to mu aburo rẹ lọ.

Sowore ni awọn darandaran ajinigbe lo ṣekọlu si aburo oun lasiko to n bọ lati fasiti Igbinedion nibi to ti n kọ iṣẹ apoogun, ki awọn ẹni ibi naa to ṣekupa a.

''Wọn ti gba ẹmi lẹnu ọmọ eniyan miran, sun ninu agbara dokita Mamiye!

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Others

''Gbogbo iwa ọdaran yoo jẹ ki idajọ awọn eniyan yii tete de ni kiakia ni''

''Emi ati iwọ ni a ma n tẹle baba wa jade nigba ti a wa ni kekere, ti o si jẹ ọmọ to nifẹ ti ko si lọta''

''Ohun gbogbo to o ṣe ni lati jẹki inu awọn to wa ni ayika rẹ dun ni gbogbo igba.''

Ajafẹtọ ọmọniyan, Omọyẹle Sowore ni aburo oun ṣiṣẹ lati jẹ ki gbogbo awọn to wa ni agbegbe rẹ wa ni alaafia, amọ iku ati ohun gbogbo ti ko dara mu ẹmi rẹ lọ ni ọsan gangan.

Sowore ṣe apejuwe ọjọ iku aburo rẹ gẹgẹ bi ọjọ ibanujẹ to gajulọ.

Bakan naa ni awọn ololufẹ rẹ loju opo ikansiraẹni Facebook ti bẹrẹ si ni fi ọrọ ikẹdun ranṣẹ si, ti wọn n ki ku ọrọ ẹni ire to lọ.

Ọmọyele Sowore ati awọn ẹbi rẹ wa lati ijọba ibilẹ Ese-odo ni ipinlẹ Ondo.