2021 UTME: Ìdí tí a ṣe fa akẹ́kọ̀ọ́ lé ọlọ́pàá lọ́wọ́ lẹ́yìn tó fẹ̀sùn kan àjọ JAMB

Oríṣun àwòrán, Oloyede
Àjọ tó n mójútó ìdánwò àṣewọle sí fásìtì (JAMB) ti fa ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún Chinedu Ifesinachi John tó jẹ ọ̀kan lára awọn tó kọ ìdánwò UTME ọdun 2021 le ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Wọ́n ṣe èyí nítorí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn pé ó yí èsì ìdánwò tó ṣe kọjá.
Sáájú ni bàbá ọmọ náà tí ni òun yóò gbé àjọ JAMB lọ sí ilé ẹjọ́ ki wọn sì san owó tó tó bílíọ̀nù kan Nàìrà fún gbígbé èsì ìdánwò tí kìí ṣe ti ọmọ òun jáde.
Ọmọ náà ti kọ́kọ́ sọ pé, èsì ìdánwò JAMB tí òun ṣe nínú oṣù keje ọdún yìí ni 380 sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé, èsì ìdánwò tí JAMB fi sọwọ́ sí oùn ni 265 lẹ́yìn tí èsì ìdánwò jáde.
Sùgbọ́n lẹ́yìn gbogbo ìwádìí 265 náà ni èsì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ, lòdì sí 380 tí o rí tẹ́lẹ̀.
Lẹ́yìn tí bàbá ọmọ yìí John Ifenkpam rí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí ló kàn sí agbẹjọ́rò kan Ikeazor Akaiwe tó fi ìpínlẹ̀ Enugu ṣe ibùjókò, láti kọ̀wé sí àjọ JAMB láti fún ọ̀dọ́mọdé náà ni àǹfàní mííràn láti tún ìdánwò náà ṣe àti pé kii wọ́n san owó ìtanràn bílíọ̀nù kan Nàìrà fún kíkọ èsì ìdánwò méjì jáde.
Ọ̀gbẹ́ni John ni láti ọdún 2019 ni wọ́n ti máa n gbé èsì ìdánwò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ọmọ náà tí wọn ko sí jẹ́ kó ní àǹfàní láti rí fásítì wọ̀ fún ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ìṣẹ̀gùn gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́.
Sùgbọ́n kàyéfì kan wáyé lọ́jọ́ Eti, nígbà tí ọmọ náà, Bàbá rẹ̀ àti agbẹ́jọrò wọn rin ìrìnàjò lọ sí ilú Abuja láti Enugu láti jẹ́ ìpè tí àjọ JAMB tí ọjọ̀gbọ́n Is-haq Oloyede pé wọ́n.
Àjọ JAMB ti kọ́kọ́ pé ọmọ náà sí kọ̀kọ̀ ni bi ti agbẹjọ́rò àti bàbá rẹ̀ náà péjú sí pé kí ó ṣàlàyé nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ nípa èsì ìdánwò 380 tó n gbé kiri, sùgbọ́n ọmọ náà kọ̀ jálẹ̀ pé èsì ìdánwò òun ni.
Lẹ́yìn onírúurú atótónu ní JAMB náà gbé ẹ̀rí ti wọ́n kalẹ̀ láti fi hàn pé irọ́ ni ọmọ náà ń pa àti pé kò sí ìgbà kan tí àwọn kọ 380 fun
Nínú ẹ̀rí tí àjọ JAMB gbékalẹ̀ ló ti fi hàn pé, 265 ni ọmọ náà gbà kìí ṣe 380 gẹ́gẹ́ bi ó ṣe ń sọ
Oloyede fi ẹ̀sùn yíyí èsì ìdánwà kan ọmọ náà, àti pé, àwọn yóò ní láti fàá lé ọlọ́páá lọ́wọ́ fún ìwádìí tó dájú àti dídá sẹ̀ríà tó bá tọ́ fún.
Ọ̀gá àgbà àjọ JAMB ṣàlàyé pé John jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mọ́kànlá mííràn tí wọ́n yí èsì ìdánwò wọn àti pé àjọ oùn yóò fi wọ́n jófin.
Ó ní àwọn yóò mú ojúlówó èsì ìdánwò tí wọ́n fún John sọ́wọ́ náà títí tí ìwádìí yóò fi pari.
Ẹ̀wẹ̀, agbẹjọ́rò rẹ̀ wá rọ àjọ náà láti túbọ̀ ṣe ìwádìí sí kí wọ́n tó ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
" Nínú ìdánwò àkọ́ka tí mo ṣe, wan fi 328 ránṣẹ́, nígbà tí ó yá,mó tún rí 278 nígbà tí mó tú lọ wòo', mo sì tẹ̀ẹ́ jáde, èyí kò lé jẹ́ kí wọ ilé ẹkọ́ iṣègun ní Fasikti Ibadan
"Ní ọdún 2020, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ṣẹlẹ̀, mó gba 343 nígbà tí mo pada pé kí lọ wòó, ó tún ti di 306, mo ló èyí láti fi wọlé sí fásítì Ibadan sùgbọ́n "Futher Mathematics" ni wan fún mi, mí o si ni èyí nínú WAEC nítori náà mo pàdànú oré-ọ̀fẹ́ láti wọlé."
" Mo gbà láti fi ìmọ̀ Isegun sílẹ̀, mó si mú ìmọ̀-ẹ̀rọ nípa epo rọ̀ọ̀bì lọ́dún 2021, èsì ìdánwò méjì ní mó tún ri, 380 àti 265.
Ẹ̀wẹ̀, ọmọkùnrin náà padà jẹ́wọ́ pé òun fi 55019 ṣe orúkọ ẹ̀gban rẹ̀ lórí fóònù, nọ́mbà náà ló wá fi kọ́ èsì ìdánwò sọwọ́ sínú fóònù ara rẹ̀.
Ó bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì, pé òun gbé ìgbésẹ̀ náà lẹ́yìn tí òun rí pé, èsì ìdánwò tí òun ní kò lé gbé wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga fún irú nǹkan ti òun fẹ́ kà.

















