Covid-19 Vaccine: Ìjọba dá àwọn Kristẹni tó ń rìnrìnàjò lọ sí Isreal padà nítorí abẹ́rẹ́ ajẹsára Covid-19

Abẹrẹ ajẹsara fun idena arun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, EPA

Awọn ọmọ orilẹede Naijiria to n rinrinajọ lọ si ilẹ mimọ, Israel ni wọn ti da pada nitori wọn ko abẹrẹ ajẹsara ti yo da abo bo wọn lọwọ arun Covid-19.

Adari Ajọ Primary Healthcare Development Agency (BASPHCDA)ni ipinlẹ Bauchi, Dr Rilwanu Mohammed lo sọ bẹẹ fun awọn oniroyin ni Bauchi.

Dokita Mohammed ni awọn ọjọgbọn mejidinlogun lati fasiti meji naa ti wọn n gbiyanju lati rin irinajo naa ni wọn ko gba ki wọn lọ, amọ ti wọn ti jọwọ ara wọn bayii lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 naa.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn eniyan ṣe kọ lati gba abẹrẹ ajẹsara naa ni ipinlẹ ọun, eleyii to mu ki wọn ko abẹrẹ ajẹsara Asrazeneca naa pamọ si inu ẹrọ amunututu to wa nipinlẹ naa.

COVID-19

Oríṣun àwòrán, Others

''O ṣeni laanu pe awọn eniyan fẹ gba kaadi to safihan pe wọn ti gba abẹrẹ ajẹsara lai gba abẹrẹ ọun, amọ ko ba ofin mu.''

Dokita Mohammed ni bi wọn ṣe da awọn kristẹni arinrinajo lọ si ilẹ mimọ ni Israel pada fihan wi pe awọn onimọ nipa eto ilẹra lagbaye to fi mọ awọn ijọba to ṣere pẹlu ilanilọyẹ pe ki awọn eniyan gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 naa.

COVID-19

O ni o da oun loju pe ni igba diẹ si isinyin kaadi idanimọ abẹrẹ ajẹsara yoo di oun ti gbogbo eniyan gbọdọ ni kaakiri agbaye, ti awọn eniyan yoo si gba bẹẹ.

''Ẹ wọ awọn ọjọgbọn mẹtadinlogun lati Faiti Abubakar Tafawa Balewa, Bauchi ati Fasiti ipinlẹ Bauchi State University ni wọn ti jọwọ ara wọn silẹ lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 naa, lọna ati le rin irinajọ lọ si orilẹede miran.''

''O di dandan ki awọn eniyan ni imọ nipa abẹrẹ ajẹsara yii nitori ahẹsọ nipa rẹ pọju, ti kii ṣi ṣe otitọ, amọ ọna lati da abo bo ara ẹni ni.''

Abẹrẹ Ajẹsara Astrazeneca

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa lo ni awọn eniyan ko fẹ gba imọran nitori awọn miran n gba abẹrẹ ajẹsara ti ileeṣẹ kan ṣe ni akọkọ, nigba to ba to asiko lati gba elekeji ni wọn yoo ma a bere fun abẹrẹ ajẹsara ti ileeṣẹ miran yatọ si eleyii ti wọn gba ni akọkọ ṣe.

Bauchi Dr Rilwanu Mohammed wa kesi awọn eniyan lati ma ṣe bẹru ti wọn ba ri ipalara bii aisan iba lẹyin ti wọn ba gba abẹrẹ ajẹsara naa tan, oun ti wọn nilo lati lo ni paracetamol.