Nigeria vs Ghana second leg live updates: Ghana sọ ìrètí Naijiria láti kópa ní World Cup 2022 di òfo pẹ̀lú 1-1

Oríṣun àwòrán, Super eagles/CAF
Ifẹsẹwọnsẹ laarin ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles orilẹ-ede Naijiria, ati akẹẹgbẹ rẹ lati Ghana, Black Stars n waye lọwọ nilu Abuja.
Ẹgbẹ agbabọọlu Black Stars lo kọkọ gba bọọlu sinu awọn nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mẹrinla.
Amọ ko ju iṣẹju diẹ lọ, lẹyin iṣẹju mẹjọ, ni Super Eagles naa fi gba bọọlu sinu awọn Ghana.
Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìfẹsẹ̀wọ́nsẹ̀ Ghana VS Nigeria tí yoò mi ìlú tìtì
Oni loni n jẹ, ẹni a bẹ lọwẹ. Taani yoo bori laarin Naijiria ati Ghana ni abala keji idije komẹsẹoyọ fun ife agbaye ọdun 2022?
Lẹyin ti Ghana ati Naijiria gbá abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ wọn ni ọsẹ to kọja nilu Kumasi, lorilẹ-ede Ghana, eyi ti wọn ti ta ọmi odo, dandan ni ki ẹnikan ninu wọn bori ni idije ti oni.
Papa iṣere Moshood Abiola ni yoo ti waye, nilu Abuja laago mẹfa irọle orilẹ-ede Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Tíkẹ́ẹ̀tì 20,000, ọkọ̀ ọ̀fẹ́ wà fún yín láti fi wòran bọ́ọ̀lù Ghana àti Nàíjíríà lọ́fẹ̀ẹ́ - Ìjọba àpapọ̀
- Kemi Afolabi ti nílò ìtọ́jú pàjáwìrì, a ń gbe lọ sókè òkun - Yomi Fabiyi bú sẹ́kún
- Agbẹjọ́rò mi yóò tẹsẹ̀ òfin bọ ìṣẹ̀lẹ̀ Shoprite àmọ́ àwọn aláṣẹ ibùdó ìtajà náà sì ń bẹ̀ mí lọ́wọ́ - Toyin Asewo to re Mecca
- "Bí agbébọn ṣe kọlu rélùwéè wa, jẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé"
- Ẹ̀mí 15 bọ́ ní Abeokuta àti Sagamu bí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣe ń ràn kiri l‘Ogun
- À ń wá láti Ibadan, wá jí ọ̀pọ̀ ọmọ gbé l‘Eko fún ètùtù ọla - Afurasi ajọmọgbe
Ẹni to ba jawe olubori ninu awọn mejeeji, yoo wa lara orilẹ-ede marun-un ti yoo ṣoju Africa ni idije ife agbaye ti yoo waye ni Qatar.
Orilẹ-ede Ghana kuna lati kopa ni idije ife agbaye lọdun 2018, botilẹ jẹ pe Naijiria ko padanu idije ife agbaye kankan fun igba mẹrin leralera.
Ẹgbẹ agbabọọlu ti goolu rẹ ba pọju laarin awọn mejeeji ni yoo lọ si idije naa.
Ti Naijiria yoo ba kopa ni World Cup , o gbọdọ bori Ghana larin aadọrun iṣẹju ti ifẹsẹwọnsẹ yoo fi waye, tabi laarin asiko ti wọn ba fun wọn si tabi nipasẹ pẹnariti.
Fun Ghana, awọn ni yoo lọ si World Cup ti
- Ifẹsẹwọnsẹ oni ba fi jẹ ọmi ayo (apẹẹrẹ 2-2)
- Ti wọn ba bori Naijiria ni Abuja
- Ti wọn ba fi bori Naijiria nipasẹ pẹnariti

Àjọ NFF àti ìjọba kó 20,000 tíkẹ́tì ọ̀fẹ́ sílẹ̀ láti wo Ghana vs Nigeria ní Abuja:

Oríṣun àwòrán, Super eagles/twitter
Ileeṣẹ to n mojuto ere idaraya ni Naijiria, ati ajọ bọọlu, NFF, ti ko ẹgbẹrun lọna ogun tikẹẹti iworan silẹ lọfẹ fun awọn to ba fẹ wo ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye laarin Ghana ati Naijiria.
Ọjọ Iṣẹgun ni ifẹsẹwọnsẹ naa yoow aye ni papa isẹre MKO Abiola to wa nilu Abuja.
Idije naa ni yoo sọ ẹni ti yoo kopa ni idije ife agbaye ti yoo waye ni orilẹ-ede Qatar.
Agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Bashir Ahmad, kọ si oju opo Twitter pe ọkọ bọọsi ọfẹ tun wa nilẹ lati ko awọn ololufẹ super Eagles lọ si papa iṣere naa.
Ibudokọ awọn bọọsi si ni wọn o ti ri tikẹẹti gba.
Ọjọ Ẹti ni abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa waye ni ilu Kumasi lorilẹ-ede Ghana. Ọmi odo ni Super Eagles ati Black Stars ta.
Ninu iroyin miran, ẹgbẹ agbabọọlu Black Stars ti gunlẹ si ilu Abuja bayii, ni imurasilẹ fun ifẹsẹwọnsẹ ọhun.


















