Abuja-Kaduna Train Attack: Àwọn èèyàn torí kó yọ nínú rélùwèé Kaduna si Abuja bá BBC sọ̀rọ̀ nípa bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé

Osinbajo lasiko to ṣe abẹwo si awọn to farapa ninu ikọlu agbesunmọmi ni Kaduna

Oríṣun àwòrán, channels tv

Igbakeji aarẹ Naijiria, Yemi Osinbajo ti sọ pe ibanujẹ ni ikọlu awọn agbesunmọmi si ọkọ reluwe kan nipinlẹ Kaduna jẹ fun oun.

Alẹ ọjọ Aje ni ikọlu naa waye lasiko ti ọkọ reluwe naa n gbe eero bi ẹgbẹrun kan lati Abuja si Kaduna.

Inu aginju Dutse, nijọba ibilẹ Chikun ni iṣẹlẹ naa ti waye, nigba to ku diẹ ki ọkọ naa de ibudokọ ti yoo apri irinajo naa si.

Lasiko abẹwo rẹ si ipinlẹ Kaduna lọjọ Iṣẹgun, Osinbajo rọ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn o ma ṣe jẹ ki iṣẹlẹ naa da omi tutu si wọ̀n ni ọkan.

Osinbajo lasiko to ṣe abẹwo si awọn to farapa ninu ikọlu agbesunmọmi ni Kaduna

Oríṣun àwòrán, channels tv

O ni "a gbọdọ titori orilẹ-ede wa, ati nitori awọn to kú tẹsiwaju ninu ija, ka si ṣẹgun awọn ojo to n ṣe ikọlu si awọn ti ko ni nkan ijagun."

Osinbajo sọ pe Naijiria ni yoo leke, ti ilẹ rẹ yoo si ni aabo.

Lasiko abẹwo naa lo tun bẹ awọn to farapa lara awọn arinrinajo naa wo ni ileewosan ti wọn gbe wọn lọ.

Ẹwẹ, ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, Usman Alkali Baba, ati olori ileeṣẹ ọmọ ogun, Ọgagun Farouk Yahaya, ti ṣe abẹwo si ibi ti ikọlu naa ti waye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi, sọ pe abẹwo naa yoo fun awọn eleto aabo ni oye ti wọn nilo lati le ṣatunṣe to yẹ, ti iru ikọlu naa ko fi ni waye mọ.

Àwọn èèyàn torí kó yọ nínú rélùwèé Kaduna si Abuja bá BBC sọ̀rọ̀ nípa bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé

Ní alẹ́ ọjọ́ Ajé ni ìròyìn gba orí ayélujára lórí bí àwọn agbébọn ṣe ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ ojú irin kan tó ń ná Abuja sí Kaduna.

Lára àwọn èrò tó wà nínú ọkọ̀ ojú irin náà sọ pé ohun gbogbo ń lọ létò létò ní ìbẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò náà kó tó di wí pé àwọn gbúro àdó olóró tó dún gbàmù lára ọkọ̀ náà.

Ọjọ́ málegbàgbé ni ó jẹ́ fún gbogbo àwa èrò inú ọkọ̀ ojú irin yẹn

Shehu Isa, ọ̀kan lára àwọn èrò náà sọ fún BBC pé ní nǹkan bí aago mẹ́fà ní ọkọ̀ ojú irin náà gbéra láti Abuja lọ sí Kaduna tí ìrìnàjò àwọn sì ń lọ dada àfi ìgbà tí àwọn dé agbègbè Dutse-Kakau tí àdó olóró sì dáhùn lára ọkọ̀ náà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ̀n.

Isa ní kò pẹ́ púpọ̀ rárá tí àdó olóró náà dún tí àwọn agbébọn náà bẹ̀rẹ̀ sí dàbọn bolẹ̀, lẹ́sẹ̀ kan náà ni gbogbo àwọn dọ̀bálẹ̀ sínú ọkọ̀.

Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló fara gba ọta àti pé òun rí àwọn ènìyàn tó ní ọgbẹ́ ìbọn lára.

Ẹlòmíràn tó tún sọ̀rọ̀, Anas Iro Danmusa tó ń fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà sórí Facebook ní àdó olóró tí àwọn agbébọn náà fi sójú ọ̀nà lágbára débi pé lọ́wọ́ kan ni éńjììnì ọkọ̀ náà bàjẹ́ pátápátá.

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

Kíni àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ reluwé sọ?

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ reluwé ní Nàìjíríà, ìyẹn Nigeria Railway Corporation lórí ẹ̀rọ̀ ayélujára Twitter rẹ̀ ní àwọn ti dá iṣẹ́ gbigbé èrò láti Kaduna sí Abuja dúró fún ìgbà díẹ̀ ná.

Gbogbo ìgbìyànjú BBC láti bá Adarí iléeṣẹ́ náà, Fidet Okhiria sọ́ra já sí pàbó nítorí fóònù rẹ̀ kò lọ.

Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn agbébọn yóò ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ ojú irin ní ọ̀nà náà

Ìgbà kejì rèé tí àwọn agbébọn yóò ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ ojú irin ní ọ̀nà náà láàárín oṣù mẹ́fà.

Nínú oṣù kẹwàá ọdún 2021, àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ ojú irin tó gbé èrò láti Kaduna lọ sí Abuja.

Àwọn ìkọlù yìí ti ń da omi tútù sọ́kàn àwọn ènìyàn nípa wíwọ́ ọkọ̀ ojú irin nítorí ọ̀pọ̀ ìjínigbé tó máa ń wáyé ní òpópónà márosẹ̀ Abuja sí Kaduna ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fi dà sí wíwọ ọkọ̀ ojú irin.

Isa tilẹ̀ bí yóò tó ọjọ́ mẹ́ta kan kí òun tó gbèrò láti rin ìrìnàjò nítorí ìbẹ̀rù àti ohun tí ojú òun rí nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ọkọ̀ ojú irin
Àkọlé àwòrán, Ọkọ̀ ojú irin

Pàtàkì ọ̀nà ojú irin Kaduna sí Abuja

Ọ̀nà ojú irin Kaduna sí Abuja nìkan ní ọ̀nà reluwé tó so Abuja pọ̀ mọ́ àwọn ìpínlẹ̀ méje tó wà ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà mọ́ ara wọn.

Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ wọ ọkọ̀ ojú irin lọ sí Abuja láti àwọn ìpínlẹ̀ Zamfara, Jigawa, Katsina, Sokoto, Kano àti Kebbi yóò kọ́kọ́ wọ ọkọ̀ dé ìpínlẹ̀ Kaduna kó tó le wọ ọkọ̀ náà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì fẹ́ràn láti máa wọ ọkọ̀ ojú irin náà nítorí ètò ààbò.

Amin iyasọtọ kan

Agbébọn kọlu rélùwéè Kaduna sí Abuja, pa ọ̀pọ̀ èèyàn, jí àwọn míì gbé lọ

Reluwe ti awọn agbebọn da lọna

Oríṣun àwòrán, @BolanleCole

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ́n oṣù kẹta ni gbẹgẹdẹ tún gbiná ní òpópónà márosẹ̀ Abuja sí Kaduna nígbà tí àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ ojú irin tí wọ́n sì jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí a kò tíì iye wọn múlẹ̀ báyìí.

Ní nǹkan bí ago mẹ́jọ alẹ́ ní àwọn agbébọn náà ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ tó kó bí ẹgbẹ̀rún kan ènìyàn.

Àwọn óṣojú mi kòró sọ pé ọkọ̀ ojú irin náà yẹ̀ kúrò lójú ọnà rẹ̀ nígbà tí nǹkan dún gbàmù lára rẹ̀ nígbà tí ó ń lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìròyìn ní àwọn ènìyàn bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ àti pé àwọn kan farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí

Orí ló kó àwọn náà yọ - àwọn èrò tó móríbọ́ ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ ṣe ṣẹlẹ̀

Àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú irin náà sọ fún BBC pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kọjá sísọ àti pé àwọn kò lè sọ ní pàtó iye ènìyàn tó kú.

Wọ́n ní ní kété tí ọkọ̀ ojú irin náà dúró ni àwọn agbébọn dàbọn bolẹ̀, tí wọ́n sì lọ já ọkọ̀ náà gbà, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jí àwọn ènìyàn gbé.

"Bí a ṣe wà lọ́nà lá gbọ́ tí nǹkan kan dún gbàmù bíi àdó olóró, tí a sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ ìró ìbọn ni àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tó wà nínú ọkọ̀ náà kojú wọn."

"A dúpẹ́ pé apá àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ká wọn díẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n ṣì rí àwọn ènìyàn jígbé sá lọ."

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn agbébọn náà pa àwọn ènìyàn ṣùgbọ́n òun kò lè sọ ní pàtó iye tó jẹ́.

A ti da àwọn ọmọ ogun sí agbègbè náà - kọmíṣọ́nà

Kọmíṣọ́nà fétò ààbò abẹ́nú ní ìpínlẹ̀ Kaduna, Samuel Aruwan nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní àwọn ti da àwọn ọmọ ogun lọ sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti lọ kó àwọn èrò tó kù àti láti lọ gbé àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

Látàrí àwọn ìkọlù tó máa ń waye ní òpópónà márosẹ̀ Abuja sí Kaduna ni àwọn ènìyàn fi ń wọ ọkọ̀ ojú irin báyìí.

Ìgbà kejì rèé tí àwọn agbébọn yóò ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ ojú irin ní ọ̀nà náà láàárín oṣù mẹ́fà.

Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante