Railway workers'strike: Wo ìdí tí àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀kọ̀ Reluwé ṣe da iṣẹ́ sílẹ̀ jákèjádò Nàìjíríà

Ibudokọ Reluwe

Nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú-irin ní Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ iyanṣẹlodi láti ṣe ìkìlọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́ta, tí wọ́n sì ti gunle èyí ní gbogbo àwọn ibùdó ọkọ̀ ojú irin káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Awọn oṣiṣẹ Nigerian Union of Railway Workers (NRC) kéde ni Ọjọrú lati da gbogbo awọn iṣẹ ọkọ oju-irin duro ni gbogbo orilẹ-ede pẹlu awọn iṣẹ lopopona Lagos-Ibadan, Abuja-Kaduna, ati awọn ọna Warri-Itakpe loni (Ọjọbọ).

Awọn ọna pataki miiran ti iṣẹ ile-iṣẹ yoo kan ni Lagos-Kano, Kano-Unguru ati Aba-Port Harcourt, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun awọn ero oju-irin ọkọ tó ń nireti lati wa ni awọn ibudo ni gbogbo orilẹ-èdè, bákan náà ni ìjọba yóò pàdánù owó tó tó aadọ́ọ́run mílíọ̀nù náírà láàárín ọjọ mẹta iyanṣẹlodi yìí.

Ni ọsẹ to kọja, ní NUR tó jẹ́ ẹka ẹgbẹ́ awọn oṣiṣẹ ni Nigeria, halẹ lati bẹrẹ idasẹsilẹ ikilọ ọlọjọ mẹta jakejado orilẹ-ede Naijiria lati ọjọ́ kejìdínlógún sì ogúnjọ́ Oṣu kọkànlá, ọdun 2021 lati tẹ awọn ẹ̀bẹ̀ wọn síwájú ìjọba.

Lati má jẹ́ ki idasẹsilẹ náà wáyé, minisita fun eto irinna, Rotimi Amaechi, ṣe ipade kan nilu Eko ni ọjọ Satide pẹlu ẹgbẹ naa, ṣugbọn a gbọ pé ipade naa forisanpọ́n nítorí ẹnu wọn kò kò.

Àkọlé fídíò, Ṣé ìrìnàjò nínú ọkọ̀ Reluwé Ibadan-Lagos-Ogun tuntun bá aráàlù lára mu? Èsì rèé

Lásìkò to ń dá àwọn akọroyin lóhùn ìbéèrè lọ́jọ́ Isegun lórí boya wọn ti da idasẹsilẹ naa duro, Aare Agba NUR, Innocent Ajiji, dahun pe ko ri bẹẹ bákan náà ló tenumo pe gbogbo awon osise oko oju irin yoo lo sile lati aago mejila owurọ loni (Thursday).

Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ ijọba n wa awọn aṣaaju ẹgbẹ NUR lọ́jọ́bọ lá ti fún wọn ní ìwé ilé ẹjọ́ kí wọn má bá gùn lè iyanṣẹlodi, ṣugbọn eyi ko laṣeyọri nitori awọn oṣiṣẹ pataki ẹgbẹ naa lọ sapamo.

Awọn adari ẹgbẹ ọhun jiyan pe aṣẹ ile-ẹjọ kii ṣe ojutu si idasesile ti a pinnu. "A ń tesiwaju pẹlu idasesile ni Ọjọbọ.

Wọn ti n gbiyanju lati jẹ ki a gba aṣẹ ile-ẹjọ kan.

Lásìkò ìbéèrè lati sọ iye awọn oṣiṣẹ ti yoo ṣe alabapin ninu idasesile naa, o dahun pe, "Awọn oṣiṣẹ bii ẹgbẹrun mọkanla (11,000).

A ni awọn oṣiṣẹ 10,995, nítorí naa a fẹrẹ to ẹgbẹ̀rún mọ́kanla.

" Lori boya idasesile naa yoo kan gbogbo awọn ibudo ọkọ oju irin ni Naijiria, Ajiji sọ pe, "Bẹẹni.

Àkọlé fídíò, Itunu Babalọla Death:Àgbáyé ẹ gbà mí, mọ fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ mí! ìyà yí tí pọ̀jù

Abuja-Kaduna, Lagos-Ibadan, Warri-Itakpe, Lagos-Kano, Kano-Unguru and Aba-Port Harcourt, gbogbo awọn ọkọ oju irin naa ni a ó duro.

Ati paapaa awọn ọfiisi wa yoo wa ni ti tipa. Ohun ti a gbo ni wi pe eka naa yoo padanu nnkan bii aadorun-un milionu naira lasiko idasesile ikilo olojo meta ati pe ti ijoba ko ba wa se bí ó ti tọ, egbe naa le kede àwọn ileese miiran kaakiri orileede yii.

"A n ṣe diẹ sii ju N360m loṣooṣu lati eka ọkọ oju-irin. A n ṣe diẹ sii ju N30m lojoojumọ," gẹ́gẹ́ bí Ajiji sọ.

O fikùn pé, "Idasesile yii yoo fa idinku ninu owo-wiwọle fun eka naa. Ṣugbọn kii ṣe ìyẹn ni kiko, èyí tó ṣe pàtàkì nínú ọrọ naa ni pe ki ijọba tẹtisi awọn ibeere wa."

Lori boya minisita naa ti kan si awọn oṣiṣẹ naa lẹhin ipade Satidee lẹ́yìn tí ìpàdé tí parí, Aarẹ NUR sọ pe, "Ko sọ nkankan titi di oni.

"A yoo wa ni awọn ibudo ni aago mẹfa owurọ ni Ojobo ati pe eyi jẹ nitori ni Abuja, fun apẹẹrẹ, ọkọ oju-irin akọkọ n gbe ni aago meje owurọ.

Nítorí naa a gbọdọ wa nibẹ ni aago mẹfa owurọ lati da ọkọ oju irin duro láti gbé èrò.

" Agbẹnusọ fun ileeṣẹ to n ri si eto irinna ti ijọba apapọ, Eric Ojekwe, sọ pe oun ko le sọrọ lori ọrọ naa. Bákan náà ni agbẹnusọ fun NRC, Yakub Mahmood, kọ lati sọ asọye eyikeyi nigbati ilé iṣẹ́ ìròyìn Punch kan si.