Kano Romance Scammer: Báyìí nì ọwọ́ ọlọ́pàá ṣé tẹ gbájúẹ̀ tó n fí ọ̀rọ̀ ifẹ́ gba fóònù lọ́wọ́ àwọn obìnrin

Aworan afurasi

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police

Ẹ tẹti bẹlẹjẹ lati gbadun iroyin yi.

Ọwọ ọlọpaa Kano ti ba arakunrin kan to n fi ọgbọn alumọkọrọyi ji foonu awọn eeyan.

Ko tan sibẹ, foonu awọn obinrin lo n ji gbe lẹyin to ba ti fi ẹtan ati jibiti kọrin ifẹ si wọn leti tan.

Gẹgẹ bi a ti ṣe gbọ, o kere tan obinrin mẹrin lo ti fi gbajuẹ gba foonu lọwọ wọn.

Lọjọ Kọkanla oṣu Kọkanla ni ọrọ yi deti igbọ awọn ọlọpaa lẹyin ti arabinrin kan ni ijọba ibilẹ Kano Municipal fẹjọ sun pe arakunrin kan t'orukọ rẹ n jẹ Muhammad ti ji foonu oun gbe.

O ni arakunrin naa parọ fun oun pe o nifẹ oun to si gba foonu tirẹ ati ti aburo rẹ pe oun yoo ra foonu tuntun mii fun wọn.

Àkọlé fídíò, Itunu Babalọla Death:Àgbáyé ẹ gbà mí, mọ fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ mí! ìyà yí tí pọ̀jù

Bi foonu ti ṣe wa lọwọ rẹ lo ba sọ pe oun sọ kọkọrọ ọkọ nu.

Ibi ti wọn ti n wa kọkọrọ ọkọ to sọnu ni Muhammad ti poora bi iso.

Aworan ọkunrin to n fi oruka si obinrin lọwọ

Oríṣun àwòrán, Gallo Images

Ninu atẹjade ti ọlọpaa fi sita, wọn ni afurasi ẹni ọdun mejilelogun yi jẹwọ ẹṣẹ rẹ lẹyin ti ọwọ awọn tẹ.

O sọ fun wọn pe ogbologbo ninu ka fi ọrọ ẹtan ba obinrin sọrọ loun jẹ ati pe oun a si maa gba foonu lọwọ wọn.

Wọn lo tun sọ pe oun ti ribi gba foonu obinrin mẹrin.

Alukoro ọlọpaa Kano DSP Abdullahi Haruna Kiyawa sọ pe awọn fimu finlẹ daada ki ọwọ to tẹ afurasi naa.

O ṣalaye pe iwadii ṣi n tẹsiwaju tawọn ko si ni pẹ lati gbe lọ si ile ẹjọ.

Labẹ ofin Naijiria, bi wọn ba da lẹbi nile ẹjọ, o le ṣẹwọn ọdun meje.