Davido: Davido ní Wema Bank ń pe òun fún ìpàdé nítorí ẹ̀dáwó N1milion tó pè sí àṣùwọ̀n wọn

Oríṣun àwòrán, davido/facebook
Gbajumọ akọrin takasufe, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido ti n da ori ayelujara ru lati Ọjọru to ti ke sawọn ọrẹ rẹ pe ki wọn da milọnu kọọkan naira fun oun ni ti ọjọ ibi oun to n bọ lọna.
Ere ati awada lọpọ eeyan pe ara ti 'ọmọ baba olowo' gbe sita yii, ṣugbọn ka to wi ka to fọ ni ojo owo ti bẹrẹ si ni rọ si aṣuwọn ifowopamọsi ti Davido fi sita fun awọn ọrẹ rẹ naa o.
- Ṣé lóòtọ́ ni ọ̀nà ti pin fún Gernot Rohr gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles Nàìjíríà?
- Alaafin Oyo fi ọkọ̀ bọ̀gìnnì dá ọmọbìnrin rẹ̀ tó gbé "First Class" jáde ní fásítì lọ́lá
- Wo ìdí tí àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀kọ̀ Reluwé ṣe da iṣẹ́ sílẹ̀ jákèjádò Nàìjíríà
- Ilééṣé ọlọ́pàá Osun tí mú Olùdarí ilé ìtura tí Akẹ́kòó fásìtì OAU ti dédé pòórá
Amọṣa ko pẹ pupọ ti ojo owo rọ ti okiki tun pe pe gbajums olorin naa ti sọrọ sita pe Banki Wema Bank to lo aṣuwọn ifowopamọsi wọn fun idawojọ naa n pe oun fun ipade.
Koda bi ikowojọ yii ṣe n gbona janjan naa ni ileefowopamọsi Wema Bank naa kanlu agbo rẹ tawọn pẹlu gbee sita pe, "Na bank wey Davido dey use we go dey use now." Eyi to tumọ si, banki ti Davido n lo lemi naa fẹ maa lo bayii.
Wo Femi Otedola, Mr Eazi, E-money, Eniola Badmus, Ikorodu bois àtàwọn èèkàn tó ti fowó ránṣẹ́ sí Davido

Oríṣun àwòrán, davido/instagram
Gbajumọ olorin Takasufe Davido ti gbe ọna kan kalẹ lati da awọn ọrẹ rẹ tootọ mọ. O ni asiko to ti oun yoo mọ awọn gan to jẹ ọrẹ oun atawọn ti ọwọ epo laraye n bani la laarin wọn.
Ninu fidio kan to fi sita, ilumọọka akọrin takasufe naa ṣalaye pe ki ọkọọkan awọn ọrẹ oun o fun oun ni miliọnu kan naira gẹgẹ bi ara ọna lati mọ awọn to jẹ ọrẹ ootọ ninu wọn.
Davido ni oun fẹ ko awọn ọrẹ oun jọ sinu lati lee lọwọ ninu riran awọn eeyan lọwọ gẹgẹ bi oun pẹlu ti ṣe maa n ṣe lati ọjọ pipẹ wa.
"Gbogbo ẹyin ọrẹ mi, miliọnu kan-kan naira!"
Iroyin kaakiri awọn ileeṣẹ iroyin abẹle n sọ pe, bi a ṣe n sọrọ yii, iye owo to ti n wọ aṣuwọn akọrin naa ti kọja aadọrun miliọnu naira.
Lara awọn eekan to ti fifẹ han si OBO bayii ni Mr Eazi, Emoney, Raimi Lateef Abiola,Nengi ti Big Brother, dorathybachor,diamondplatnumz, focalistic lati south Africa, stanleyenow lati cameroun ati bẹẹlọ.
Awọn ikorodu bois naa fi ẹgbẹrun marun ranSẹ.

Oríṣun àwòrán, davido/facebook
Gbajumọ olorin naa ni miliọnu mẹwaa loun ti ri laarin isẹju meje.
O ni awọn to ba lee fun oun ni miliọnu kan naira lara awọn ọrẹ oun loun mọ ni ọrẹ tootọ
Davido ni ọgọrun miliọnu naira loun nilo ni ikowojọ naa.













