Alaafin of Oyo: Alaafin fún ọmọbìnrin rẹ̀ tó gbé ipó "First Class" jáde ní fásítì lẹ́bùn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́

Oríṣun àwòrán, other
Alaafin Oyo, Oba Lamidi Adeyemi ti fi ọkọ bọginni kan da ọmọbinrin rẹ, Zainab Adebunmi Adeyemi lọla lẹyin to gbe ipo kinni (First Class) jade ni fasiti Lead to wa niluu Ibadan.
Ninu ẹkọ imọ nipa ẹya ara eeyan ni Adebunmi ti kẹkọọ gboye fasiti akọkọ jade.
Alaafin fi ẹbùn ọkọ naa mọ riri iṣẹ takuntakun ti Adebunmi ṣe eleyii to fi pegede ninu ẹkọ rẹ.
- Gbájúẹ̀ tó ń fi ọ̀rọ̀ ifẹ́ lu àwọn obìnrin ní jìbìtì ní Kano kó s'ọ́wọ́ Ọlọ́pàá
- Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, Ijọba Eko sọrọ lórí àbọ̀ ìgbìmọ̀ igbẹjọ́ lórí #EndSARS
- Ilééṣé ọlọ́pàá Osun tí mú Olùdarí ilé ìtura tí Akẹ́kòó fásìtì OAU ti dédé pòórá
- 'Ó ṣeéṣe kí ẹ̀dà ìwé àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ EndSARS tó lu sórí ayúlujára yàtọ̀ sí èyí t'íjọba yóò gbé jáde'
Ọmọbabinrin Adebunmi bu si ẹkun ayọ ti o si fi ikunlẹ bẹ lati dupẹ lọwọ Ikubabayeye.
Iroyin sọ pe Eledumare fi ọpọlọ pipe jinki Adebunmi ninu ẹkọ to ti gboye jade ati ninu awọn ẹkọ miran.
Ọmọbabinrin Adebunmi dupẹ lọwọ Eledua fun ore ọfẹ to ni, bakan naa lo tun dupẹ lọwọ Alaafin ati Olori Ramat Adedayo Adeyemi fún ipa ribiribi ti wọn ko ninu igbe aye rẹ.
O ni bi wọn ṣe wo oun dagba pẹlu ọgbọn ati ìmọ Ọlọrun wa lara awọn nkan to ran oun lọwọ lati tayọ lẹnu ẹkọ oun.
Adebunmi ni "awọn nkan ti wọn ti fi kọ mi lati ilẹ lo fun mi lagbara lati le kọju si iwe mi ju awọn ẹgbẹ mi lọ.
Ni aafin Oyo ni ayẹyẹ ẹbun ọkọ ti Alaafin fi ta Adebunmi ti waye.
Alaafin gan an ti lọ fun ayẹyẹ ikẹkọọ jade fasiti Lead tẹlẹ ni Ibadan ki o to wa fun ọmọbinrin rẹ ni ẹbun ọkọ.













