Gernot Rohr: Ṣé lóòtọ́ ni ọ̀nà ti pin fún Gernot Rohr gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles Nàìjíríà?

Gernot Rohr

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to n jade sori ayelujara bayii n sọ pe o ṣeeṣe ki ajọ ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF ti yọ akọnimọọgba ikọ Super Eagles, Gernot Rohr kuro nipo.

Iroyin naa n sọ pe ajọ NFF ti gbe igbesẹ lori yiyọ ọ ni ipo lẹyin ti awọn esi ti ikọ Super Eagles tiraka rapala wọ ipele to kan lati kopa ni idije ife ẹyẹ agbaye Qatar 2022.

Amọṣa bi iroyin yii ṣe n jade lawọn iroyin miran tun n jade pe ko ri bẹẹ.

Koda awọn ileeṣẹ iroyin ere idaraya labẹle bii Sporting Sun ṣalaye pe agbẹnusọ fun ajọ NFF, Ademọla Olajire sọ fun ileeṣẹ iroyin naa pe ko si ohun to jọ ọ.

O fi kun un pe o di igba ti igbimọ to ga julọ lajọ NFF ba ṣe ipade ki wọn to lee gbe irufẹ igbesẹ bẹẹ lati gba iṣẹ lọwọ akọnimọọgba Gernot Rohr.

Amọṣa iroyin to n tẹ BBC News Yoruba lọwọ lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ n sọ pe ipade igbimọ naa n lọ lọwọ. Sugbọn a ko lee sọ boya ọrọ nipa rirọ akọnimọọgba Super Eagles naa nipo ni wọn pe ipade yii le lori tabi boya o wa ninu awọn ọrọ ti wọn yoo jiroro le lori nibẹ.

Àkọlé fídíò, Latifat Tijani: Ìjọba Naijiria ń ṣèlérí láti mọ́ rírì mi àmọ́ láti 2016, pàbó ló ń já sí