African World Cup qualifiers: Pẹnáritì gbé Super Eagles borí Liberia pẹ̀lú góòlù méjì sí òdo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles tun ṣe kẹrẹkẹrẹ sun mọ ipele to kan ninu ifẹsẹwọnsẹ lati mọ awọn orilẹede wo ni yoo kopa ni idije ife ẹyẹ bọọlu agbaye lọdun to n bọ.
Nibi ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu awọn ikọ Lone Stars ti Liberia ni ilu Tangers lorilẹede Morocco, ikọ Super Eagles bori pẹlu goolu meji.
Victor Osimhen lo gba goolu akọkọ wọlu pẹlu pẹnariti nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju karundinlogun ki Ahmed Musa to fọba lee pẹlu pẹnariti miran nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinlelaadọrun.
Pẹlu esi ifẹsẹwọnsẹ yii orilẹede Naijiria lo n leke ipin 'C' bayii pẹlu ami mejila ti Cape Verde, Central African Republic ati Liberia si n tẹle pẹlu ami mẹwaa, mẹrin ati mẹta ni ṣisẹ n tẹle.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ilu Tangers lapa ariwa orilẹede Morroco ni ifẹsẹwọnsẹ naa ti waye lẹyin ti ajọ ere bọọlu afẹsẹgba lagbaye sọ pe papa iṣire to wa ni ilu Monrovia lorilẹede Liberia ko ku oju iwọn rẹ.









