Nigeria vs Central African Republic: Super Eagles fìdírẹmi ní pápá ìṣeré Teslim Balogun

Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Akẹhinde gbẹgbọn ni awọn agbabọọlu orilẹ-ede Central African Republic fi ọrọ wọn ṣe, pẹlu bi wọn ṣe na Naijiria ni ami ayo kan si odo ni papa iṣere Teslim Balogun nilu Eko.

Karl Namganda lo gba bọọlu gba bọọlu kan ṣoṣo to wọ inu awọn lasiko ifẹsẹwọnsẹ naa.

Ṣaaju ki wọn o to o fiya jẹ Naijiria, ko si orilẹ-ede kankan to ti i na Naijiria lati igba ti idije World Cup Qualifier ti bẹrẹ.

Wọn bori idije meji akọkọ ti wọn gba ni ipin C.

Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn ti gba bayii, Naijiria lo ṣi n lewaju ipin naa pẹlu ami mẹfa, ti Cape Verde si wa ni ipo keji pẹlu ami mẹrin.

Ami mẹrin naa ni Central African Republic ni, ṣugbọn iye igba ti wọn gba bọọlu sinu awọn kere si ti Cape Verde.

Liberia lo wa ni ipo to kere ju nitori ami kan ṣoṣo ti wọn ni.