Lẹ́yìn ìfìdírẹmi ọ̀sẹ̀ tó kọjá, Man Utd fìkanra dá bàǹtẹ́ ìyà fún Tottenham mọ́lé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Manchester United ti tun ọmọluabi wọn ṣe bi wọn ti ṣe gbewuro soju Tottenham Hotspur pẹlu goolu mẹta sodo.
Lọsẹ to kọja ni wọn faragbaya goolu marun un si odo lọwọ Liverpool amọ bayi wn gbọn ara nu ti wọn si da bantẹ iya fun Tottenham.
Pẹlu aṣeyọri yi, Man United ti bọ si ipo karun lori afara ti Arsenal si wa lẹyin wọn ni ipo Kẹfa.
Cristiano Ronaldo lo ṣide goolu fun United ti Edison Cavani naa si tẹle.
Rashford to wọle fun Cristiano Ronaldo lo de ifẹsẹwọnsẹ naa lade pẹlu goolu Kẹta.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alatilẹyin Tottenham n kọrin eebu fawọn agbabọọlu wọn nitori bi wọn ko se ṣe daada lori papa.
Pẹlu esi yi, Man United bọ si ipo Karun,Chelsea ṣi le tente lori afara ti Liverpool naa si n tọ wọn lẹyin.

Oríṣun àwòrán, EPA
Ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ mii, Crystal Palace gbe ija lọ ba Manchester City nile wọn ti wọn si jẹ goolu meji ni Etihad.
Liverpool to kọkọ jo pada wa n mi hẹlẹhẹlẹ ni pẹlu bi Brighton ti ṣe da goolumeji pada ti wọn si gba ọmi.
Arsenal vs Leicester: Arsenal fi Leicester gun òkè afárá líìgì sí ipò kàrún,2-0 ló bá dé
Aṣọle Arsenal Aaron Ramsdale lawọn eeyan n mọrọ rẹ bẹnu pẹlu bi ẹgbẹ agbabọọlu naa ṣe da bantẹ iya goolu meji si odo fun Leicester City.
Idi ni pe aṣọlẹ yi da bi ẹdun to si rọ bi owe ninu ipade wọn nile Leicester City lọjọ Abamẹta yi.
Ọpọ igba lo kọdi awọn atamatase Leicester City to gbiyanju lati pa odo rẹ ṣugbọn paboi ni o ja si.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi Arsenal ti ṣe pegede ninu ifẹsẹwọnsẹ yi ti wa mu ki wọn sun soke si ipo kaarun lori afara Premier League.
Goolu mejjeji wa ninu abala kini ifẹsẹwọnsẹ naa to ṣide awọn ifẹsẹwọnsẹ́ to waye lopin ọsẹ yi.
Gabriel lo kọkọ fi ori kan bọọlu si awọn Leicester nigba ti Bukayo Saka gba kọna kan si oju ile Leicester.
Saka yi kanna ati Alexandre Lacazette ni wọn jijọ pawọ pọ tẹ bọọlu kalẹ si Emile Smith Rowe to fi ẹsọ pẹlẹ gba si awọn.
Ninu ifẹsẹwọnsẹ meje ti Arsenal gba sẹyin, wọn ko ti fidirmi ninu rẹ.
Lati ipo Kẹwa ti wọn wa tẹlẹ, ọfẹ ti gbe wọn pa ti wọn si ti wa ni ipo karun un bayi lori afara.
Leicester ni ti wọn ko tilẹ ta putu ninu ifẹsẹwọnsẹ naa paapa lawọn iṣẹju ibẹr ipade naa.
Eleyi kun ohun ti Arsenal fi tete ribi rọ bajinatu goolu meji si awọn wọn laarin ogun iṣju ifẹsẹwọnsẹ wọn.












