Arsenal vs Tottenham: Arsenal jẹ́wọ́ òǹnilẹ̀ North London han Tottenham pẹ̀lú àmì ayò 3-1

Agbabọọlu Arsenal, Bukayọ Saka n ṣe ajọyọ goolu rẹ

Oríṣun àwòrán, Premierleague.com

Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal gbo ewuro soju alamuleti wọn ni iha ariwa ilu London, iyẹn ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham Hotspur pẹlu ami ayo mẹta si ẹyọ kan.

Ifẹsẹwọnsẹ naa to waye ni papa iṣire Emirates to jẹ ibuba Arsenal jẹ ọkan lara awọn ifẹsẹwọn to maa n fa ariyanjiyan ati awuyewuye julọ ninu idije Premier league ilẹ Gẹẹsi.

Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kejila ni Smith Rowe, agbabọọlu Arsenal gba goolu akọkọ wole. Eyi lo si mu ko di agbabọọlu to kere julọ ni ikọ Arsenal ti yoo gba bọọlu sawọn ni ifẹsọwọnsẹ laarin Arsenal ati Tottenham. Ẹni ọdun mọkanlelogun o le ọgọta ọjọ ni Emile Smith Rowe.

Nigba to di iṣẹju kẹtadinlọgbọn ni balogun ikọ Arsenal naa, Piere-Emerick Aubameyang gba goolu keji fun Arsenal.

Awọn ololufẹ Arsenal n ṣe ajọyọ

Oríṣun àwòrán, Premierleague.com

Bukayọ Saka lo fi ọba lee fun Arsenal nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinlelọgbọn ki wọn to lọ fun isinmi abala akọkọ.

Amọṣa nigba ti abala keji wọle de, awọn agbabọọlu Tottenham hotspurs gbọnra jigi ṣugbọn gbogbo itabiọbiọ wọn, goolu kan ṣoṣo ni wọn ri da pada nibẹ.

Son Heun-min lo gbaa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kọkandinlọgọrin.