Nigeria vs Cape Verde: Super Eagles rápálá wọ ìpele kómẹsẹ̀-ó-yọ Qatar 2022, ọ̀mì ni wọ́n ta pẹ̀lú Cape Verde l'Eko

Ikọ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọ agbabọọlu Naijiria, Super Eagles tun rapala wọ ipele to kan ninu ifẹsẹwọnsẹ lati mọ awọn orilẹede wo ni yoo kopa ni idije ife ẹyẹ bọọlu agbaye lọdun to n bọ.

Nibi ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu awọn ikọ Cape Verde ni papa iṣere Teslim Balogunto wa nilu Eko, ikọ Super Eagles ta ọmi.

Victor Osimhen lo gba goolu akọkọ wọle nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa ko tilẹ tii pe iṣẹju kan ki Júlio Tavares to daa pada nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju karun un.

Pẹlu esi ifẹsẹwọnsẹ yii orilẹede Naijiria ti kogoja lati kopa ninu ipele komẹsẹ-o-yọ ti yoo waye laarin awọn orilẹede to leke ipin kọọkan ipele to pari yii.

Atẹ igbelewọn ipin 'C'

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oṣu kẹta ọdun 2022 ni ipele naa yoo bẹrẹ.