Human body parts: Ọmọbìnrin rí ara èèyàn nínú fìríìjì ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀

Oríṣun àwòrán, South african police
Oriṣiiriṣii lo n ṣẹlẹ ní duniyan ti a wa yii.
Ọmọbinrin kan lo ba ara eeyan ninu firiiji ọrẹkunrin rẹ niluu Soweto lorilẹede South Africa.
Ọmọkùnrin náà, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ti ko si gbaga ọlọpaa bayii niluu Soweto.
Awọn ọlọpaa mu ọkunrin naa lọjọ Abamẹta lẹyin ti wọn ri ara eeyan to di sinu baagi ninu firiiji ninu yara to gba.
- Àwọn ajínigbé pa èèyàn méjì l’Akure, ẹnìkan móríbọ́, ẹnìkan ṣì wà ní ìkáwọ́ wọn
- Kò ní sí ọ̀rọ̀ òkú òru lórí àbájáde ìwádìí nípa #EndSARS, Lekki Toll Gate, Sanwo-Olu ṣèlérí fárá Eko
- Gbèdékè ọ̀ṣẹ̀ mẹ́ta la fún ìjọba Buhari láti sanwó oṣù òṣìṣẹ́, ìyanṣẹ́lódì ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ASUU ń rúgbó bọ̀!
- Ilé ẹ̀kọ́ Fásítì Unilorin fọwọ́ òsì júwe ilé fún akẹ́kòó tó lù olùkọ lálùbami
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọmọbinrin to jẹ ọrẹbinrin ọkunrin naa ni ri awọn ara eeyan yii ninu firiiji nigba ti ọkunrin ọhun fi í silẹ lọ sí ọja.
Ọmọbinrin naa ri ara eeyan nigba to n wa ounjẹ ti o le jẹ.
Iroyin kan tiẹ sọ pe ọmọkunrin ọhun kun ara rẹ ni ọbẹ nigba ti wọn fẹ mu un.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Brigadier Brenda Muridili ni ọmọkunrin yoo foju ba ile ẹjọ lori ẹsun ipaniyan laipẹ.
Muridili ṣalaye pe ko si ẹni to le sọ ara ẹni ti ọkunrin yii gbe sí inu firiiji.
Amọ, o ni iwadii ti nbẹrẹ lori ẹya ọhun lati ti le ẹni to jẹ gan an.
Bayii ọmọbinrin yii ṣe ri ara eeyan ninu firiiji ọrẹkunrin rẹ
Ọrẹkunrin rẹ ni a gbọ pe ọkunrin yii pe wí pe ko wa ṣe isinmi opin ba ọsẹ nile oun.
Nigba ti ọkunrin yii jade ni ọmọbinrin naa ri ara eeyan ninu firiiji eleyii to ba a l'ẹru gan an.
O pariwo lẹyin to ri ara eeyan tan, o sí sare kaba kaba lọ ba ara ile kan to n jẹ Sarah Marumole lati rẹ ẹ lẹkun.
Sarah ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin SABC ni South Africa pe ṣadeedee ni omobinrin naa sare wọ ile awọn ti o si n gbọn.
O ni ọmọbinrin yii bẹrẹ si ni pọ bi o ti n gbọn.
"Ọlopaa ni ọkan lara awọn alabagbe to wa ba wa nibi ile ọkunrin yii.
Ẹlomiran naa tun darapọ mọ wa ti gbogbo wa si duro ti ọmọkunrin ọhun fi de lati ọja to lọ.
Bayii ni wọn ṣe mu ọmọkunrin yii to gbe ara eeyan pamọ́ sí inu firiiji o," Sarah ṣalaye.














