Ondo kidnappers: Àwọn agbébọn pa èèyàn méjì l’Akure, wọ́n ṣá ẹlòmíràn ní àdá lórí

Oríṣun àwòrán, other
Awọn ajinigbe ti ṣa okunrin meji kan pa niluu Ala, lẹba ilu Akure, nipinlẹ Ondo.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Odunlami Ibukun ṣalaye fun BBC Yoruba pe awọn mẹrin ni awọn ajinigbe naa ṣakọlu si, ṣugbọn ẹnikan moribọ ninu wọn, ẹnikan wa ni ikawọ awọn naa nigba ti awọn meji ti jade laye.
O ni "Iṣẹlẹ naa ṣeni laanu gidi gan, lana ni a gbọ pe wọn ṣa okunrin kan ni ada niwaju ori rẹ, a si gbe okunrin ọhun lọ sile iwosan."
"Lẹyin naa ni a gbọ pe mẹrin ni wọn, ati pe maalu ni wọn fẹ lọ ra ki ikọlu naa to waye."
"Ko pẹ ti a gbe iwadii dide ti a ṣawari oku awọn okunrin meji ninu igbo ti iṣẹlẹ naa ti waye, ti wọn jẹ meji lara awọn mẹrin ti awọn ajinigbe naa kọlu."
"Ẹgbẹ awọn alapata ti fi to wa leti pe awọn ajinigbe ọhun ti pe awọn lati fi to awọn leti pe ikawọ awọn ni ẹnikan to ku wa."
- Nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà yóò fi dé, ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, ẹ̀mí ti sùn - Òṣíṣẹ́ ní Mushin
- Ilé ẹ̀kọ́ Fásítì Unilorin fọwọ́ òsì júwe ilé fún akẹ́kòó tó lù olùkọ lálùbami
- Lóòtọ́ ni wọ́n de òkú táa gbé jáde nínú odò Asa, Ilorin lọ́wọ́ àti ẹnu - Ilééṣé ọlọ́pàá
- Boko Haram gbàjọba ní ìlú Shiroro áti Rafi ní ìpínlẹ̀ Niger l'ẹ́bá Ilorin
Odunlami sọ pe iwadii ti bẹrẹ, awọn yoo si gbiyanju lati doola ẹnikan to wa ahamọ awọn ajinigbe ọhun, ati lati fi ṣikun ofin mu awọn afurasi naa.
bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ?
Ẹwẹ, Nasiru Jamiu, to jẹ okunrin to moribọ ninu awọn okunrin mẹrin ti iṣẹlẹ naa ṣẹ si ti ṣalaye fun awọn akọroyin niluu Akurẹ bi ọrọ naa ṣe jẹ.
O ni "Awọn ajinigbe ọhun pe awọn ọga mi lori ago lati wa ra maalu, a si tẹkọ leti lọ bawọn, ṣugbọn ni kete ti a de ibẹ ni wọn ṣina bolẹ ti wọn si ji ọga mi gbe lọ sinu igbo."
Gẹgẹ bii ohun to sọ, lasiko ijinigbe ọhun ni wọn ṣa ni ada lori, ṣugbọn o da bii ọgbọn lati ṣe bii ẹni to ti ku titi ti awọn ajiigbe ọhun fi wọ inu igbo lọ.
Jamiu ni "Awa mẹta gbiyanju lati salọ ṣugbọn wọn ṣa mi ni ada, mo si ṣubu lulẹ, mo dibọn bii ẹni ti ẹmi ti bọ lara rẹ."
"Lẹyin ti mo ri pe ko si ẹnikẹni mọ lagbegbe naa ni mo dide, ti mo si bẹrẹ si n salọ ninu igbo."
Okunrin naa pari ọrọ rẹ pe oju oun koro ni wọn ji ọga oun gbe lọ sinu igbo ṣugbọn oun ko le sọ ni patọ ibi ti awọn okunrin to ku wa.
O ni "Mo ri nigba ti wọn n gbe ọga mi lọ, sugbọn ni ti awa to ku, mi o mọ ibi ti awọn okunrin meji naa wa, boya wọn ti ji awọn naa gbe ni o tabi wọn ti pa wọn, mi o le sọ."
Ni iroyin kan naa, agbẹnusọ ọlọpaa l'Ondo ni awọn ko tii le fidi rẹ mulẹ boya awọn Fulani darandaran lo wa nidi iṣẹlẹ ijinigbe naa, tabi awọn ẹgbẹ mii.













