Boko Haram gbàjọba ní ìlú Shiroro áti Rafi ní ìpínlẹ̀ Niger l'ẹ́bá Ilorin

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi Boko Haram ti gba iṣakoso abule marun un ni ijọba ibilẹ Rafi ato Shiroro, nipinlẹ Niger.
Akọwe ijọba ipinlẹ ọhun, Alhaji Ahmed Matane lo fi ọrọ naa to awọn akọroyin leti niluu Mina lasiko to n ba ileeṣẹ News Agency of Naijiria sọrọ.
Matane sọ pe awọn agbesumọmi naa ti gbajọba niluu Hanawanka ati Madak ni Rafi, ati Kurebe, Gussauto fi mọ Farina Kuka ni Shiroro, eyii to mu ki awọn olugbe agbegbe naa ma fi ile wọn silẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ni ṣe ni awọn agbesumọmi ọhun n yan fanda lawọn agbegbe ọhun pẹlu iniruru ohun ija oloro lọwọ wọn lai si idiwọ Kankan.
O ni ijọba ipinlẹ naa ti fi ọrọ ọhun to awọn agbofinro leti lati le wa nnkan ṣe si ọrọ naa.
Lẹyin ti awọn agbesumọmi ISWAP ṣekupa ọgagun Brig-Gen. Dzarma Zirkusu atawọn ọmọ abẹ rẹ, awọn ọmọ ogun ti pada si agbegbe ọhun, nibi ti wọn ti pa nnkan bii aadọta lara awọn agbesumọmi naa ni ijọba ibilẹ Askira Uba, ni ipinlẹ Bornu.
Matane sọ pe ibinu ni awọn ọmọ ogun fi pa awọn agbesumọmi ọhun, eyii ti ọgagun Brig-Gen. Onyema Nwachukwu dari rẹ.
Ṣaaju ni ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun Naijria, Lt-Gen. Farouk Yahaya ti kọkọ ṣabẹwo si mọlẹbi ọgagun ti awọn ọmọ ikọ ISWAP ṣekupa ọhun.
Ni iroyin miran, gomina ipinlẹ Bornu, Babagana Zulum, ti sun ayẹyẹ ṣiṣi awọn iṣẹ akanṣe kan, eyii to yẹ ko waye siwaju lati kẹdun awọn ọmọ ogun ti ẹmi wọn sọnu.
Agbẹnusọ Zulum, Isa Gusau sọ pe gomina naa yoo lọ bẹ mọlẹbi awọn ọmọ ogun ti ẹmi wọn sọnu wo kaka ko lọ ṣi awọn iṣẹ akanṣe naa.
Ẹwẹ, olori ẹlẹsin Musulumi, Sheikh Ahmad Gumi ti ni iwa janduku le di ohun itan ni Naijiria ti ijọba ba le pese ẹkọ to peye fun awọn janduku naa bi wọn ṣe n jọwọ ohun ija wọn.
Gumi sọ pe ni ṣe lo yẹ ki ijọba gbe owo gọbọi kalẹ fun idanilẹkọọ ati atunṣe aye awọn janduku naa kaka ko maa na obitibiti owo lori ileeṣẹ ọmọ ogun lati ra awọn ohun ija oloro.
Olori ẹlẹsin naa lo fi ọrọ ọhun lede ni gbagede Sheikh Uthman Bin Fodio Centre, to jẹ ile ẹkọ Musulumi to kọ fun awọn Fulani daran-daran ni abule Kohoto.

















