Yoruba Nation: Kò sí Ilana Omo Oodua mọ́ ní UK, a fẹ́ ṣe àtúnṣe - Ilana Ọmọ Oodua

Oríṣun àwòrán, Ìlànà Ọmọ Oòduà International Facebook
Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ti kede wi pe awọn fẹ tu igbimọ ẹgbẹ Ilana Yoruba to wa ni Ilẹ Gẹẹsi ka ki wọn le ṣe atunto to peye.
Ninu atẹjade ti ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua Worldwide gbe jade gba ọwọ akọwe ẹgbẹ, Maxwell Adeleye ni wọn ti fi aṣẹ tuntun naa jade.
Adari ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Banji Akintoye ni oun ti fi ọwọ si ituka igbimọ ẹgbẹ naa ni Ilẹ Gẹẹsi ni kiakia.
- Sunday Igboho: Ìjọba Buhari ló ní ẹ̀bi, ẹ yé dá ẹ̀bi ru àwọn tó ń bèèrè fún 'Yoruba Nation'
- Sheikh Gumi kọ́ ilé ẹ̀kọ́ fáwọn Fulani Darandaran nínú igbó Kaduna
- Wo bí ọ̀rọ̀ ikú ọmọbìnrin tó fẹ́ fa àríyànjiyàn láàrín Nàìjíríà àti Ivory Coast ṣe jẹ́
- Ọgbọ́n ni mo ń dá láti yẹra fún gbọ́yísọ̀yí lágbo òṣèré - Ijebu
- Bode George, j'ógun ó mí, gbà f'ọ́gàá ẹ, yé tako Asiwaju Bola Tinubu mọ́- Joe Igbokwe
Wọn ni idi ti awọn fi gbe igbesẹ naa ni wi pe ki wọn le e ni ẹgbẹ ọmọ ilẹ Yoruba to gbooro ni Ilẹ Gẹẹsi nitori orilẹede naa pọn dandan si ijijagbara wọn, ti wọn si gbọdọ mojuto bi o ṣe n lọ ninu ẹgbẹ naa.
''A gbe igbeṣẹ naa ki ihuwasi to le e ba ohun gbogbo ti a n ṣe jẹ ma ba waye nitori awọn ọmọ Yoruba ni ile ni oko n gbiyanju loriṣirisi lati ri pe ẹgbẹ naa ko dojubole''

Oríṣun àwòrán, Facebook
''Ilẹ Gẹẹsi si pọn dandan si ẹgbẹ ọmọ Yorubam nitori naa ni a o gbe igbimọ tuntun miran kalẹ ti yoo bojuto ẹgbẹ naa ni Ilẹ Gẹẹsi.''
''Bakan naa ni a n fi asiko yii kede pe Arabinrin Shola Salako kii ṣe adari ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ni oke okun.''
- Ta lo tún ti ilé ijó Obi Cubana l'Abuja pa?
- Human Trafficking Series: Ìrírí àrábìnrin kan àti ọmọ rẹ̀ lásìkò tí wọ́n tà wọ́n sí Lebanon àti Libya
- Kìí ṣe oògùn ìbílẹ̀ ni mo fi ń rántí déètì ọjọ́ àti oṣù lórí, ohun tí mo ṣe nígbà èwe rèé - Alaafin Oyo
- Ìdí rèé tàwọn akẹ́kọ̀ọ́ òde òní ń gbéná wojú Ọ̀gá, dá sẹ̀ríà fáwọn olùkọ́ wọn- Ónimọ̀ àyẹwò ọpọlọ
- Ọmọ mi ti kọ́kọ́ bọ́ra sí hòhò l'àdúgbò, àbúrò rẹ̀ ń mójú tóo nílé ló sá lọ lu Lẹ́ksọrà lọ́jọ́ kejì - Baba Captain Walz
''Arakunrin Akin Wilson naa kii ṣe adari kankan ninu ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua mọ ni Ilẹ Gẹẹsi.''
Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua wa kede pe ẹnikẹni to ba ba awọn mejeeji naa ṣe pọ yoo wa ni aye ara wọn kii ṣe ti ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua.












