ASUU Strike: Gbèdékè ọ̀ṣẹ̀ mẹ́ta la fún ìjọba Buhari láti sanwó oṣù òṣìṣẹ́, ìyanṣẹ́lódì ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ASUU ń rúgbó bọ̀!

Oríṣun àwòrán, Twitter
Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti lorilẹede Naijiria, ASUU ti fun ijọba aarẹ Buhari ni gbedeke oṣẹ mẹta lati fi dahun si ibeere awọn oṣiṣẹ ki wọn to gunle iyanṣelodi..
Aarẹ ẹgbẹ ASUU, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke lo fi eyi lede fun awọn oniroyin ni ilu Abuja.
Osodeke kilọ wi pe ti ijọba ko ba dahun si ibeere wọn lori adehun ti wọn jọ buwọlu ni Osu Kejila, ọdun to kọja, eleyii to mu ki awọn gebgile iyanṣelodi naa ni ọdun 2020 ọhun.
- Sunday Igboho: Ìjọba Buhari ló ní ẹ̀bi, ẹ yé dá ẹ̀bi ru àwọn tó ń bèèrè fún 'Yoruba Nation'
- Boko Haram gbàjọba ní ìlú Shiroro áti Rafi ní ìpínlẹ̀ Niger l'ẹ́bá Ilorin
- Lóòtọ́ ni wọ́n de òkú táa gbé jáde nínú odò Asa, Ilorin lọ́wọ́ àti ẹnu - Ilééṣé ọlọ́pàá
- Kò sí Ilana Omo Oodua mọ́ ní UK, a fẹ́ ṣe àtúnṣe - Ilana Ọmọ Oodua
- Sheikh Gumi kọ́ ilé ẹ̀kọ́ fáwọn Fulani Darandaran nínú igbó Kaduna
Amọ ẹgbẹ ASUU ni ti ijọba ko ba dahun si ibeere wọn yii, awọn yoo gunle iyanṣelodi miran.
Gẹgẹ bi ọrọ aarẹ ẹgbẹ ASUU, ohun ti wọn n bere fun ni ki ijọba san awọn owo ajẹmọnu ti wọn ṣe adehun pe awọn to san ati owo to tọ si idagbasoke awọn ileẹkọ giga fasiti ni Naijiria.
Gbedeke tuntun yii ni ẹgbẹ ASUU fi lede lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu igbimọ amuṣeya (NEC) ẹgbẹ naa ni ilu Abuja.

Oríṣun àwòrán, Emmanuel oloye
Osu Kẹta, ọdun 2020 ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU gunle iyanṣẹlodi lẹyin ariyanjiyan pẹlu ijọba apapọ lori aimu adehun wọn ṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ ati ọrọ asuwọn owo kan naa ti ijọba ti fẹ ma a san owo oṣiṣẹ, iyen Integrated Payroll and Personnel Information System (IPPIS).
Amọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU gba si ijọba lẹnu lati lo asunwọn owo University Transparency and Accountability Solution (UTAS), eleyii ti yoo rọpọ IPPIS.
Eleyii mu ki ijọba apapọ ṣe ipade pẹlu wọn lasiko naa lọna ati koju iyanṣẹlodi to ti n lọ fun ọpọlọpọ oṣu, ti wọn si jọ ni adehun.
- Wo bí ọ̀rọ̀ ikú ọmọbìnrin tó fẹ́ fa àríyànjiyàn láàrín Nàìjíríà àti Ivory Coast ṣe jẹ́
- Bode George, j'ógun ó mí, gbà f'ọ́gàá ẹ, yé tako Asiwaju Bola Tinubu mọ́- Joe Igbokwe
- Ta lo tún ti ilé ijó Obi Cubana l'Abuja pa?
- Ọgbọ́n ni mo ń dá láti yẹra fún gbọ́yísọ̀yí lágbo òṣèré - Ijebu
- Kìí ṣe oògùn ìbílẹ̀ ni mo fi ń rántí déètì ọjọ́ àti oṣù lórí, ohun tí mo ṣe nígbà èwe rèé - Alaafin Oyo
Lẹyin naa ni wọn wọgile iyanṣẹlodi olosu mẹsan naa ti ijọba ṣe ileri iye owo to to aadọrin biliọnu naira lati san owo awọn oṣiṣẹ naa, ati lati mu idagbasoke ba awọn ileẹkọ giga fasiti kaakiri Naijiria.
Amọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ASUU kilọ fun wọn wi pe awọn yoo gunle iyanṣelodi miran, ti ijọba ko ba mu adehun wọn ṣẹ.












