Ilé ẹjọ́ jú bàbá ẹni ọdún 72 di èrò ẹ̀wọ̀n ní Ilorin nítorí ayédèrú ìwé ìrìnnà ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, others
Ile ẹjọ majisireti kan to n wa nilu Ilorin, nipinlẹ Kwara, ti ju baba ẹni ọdun mẹtalelaadọrin kan si ẹwọ ọdun meji.
Wọn fi ẹsun kan Bashir Alabi pe wọn ba ayederu iwe irinna ọkọ lọwọ̀ rẹ.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin abẹle, The Punch ṣe sọ, adajọ tun paṣẹ ki wọn o ku awọn mẹta mii, Ogunmoroti Akindele, to jẹ oniṣowo ni agbegbe Kilanko, nilu Ilorin, Idowu Adebisi, to ni ibudo itẹwe igbalode kan, ati Joshnson Ariyo, tẹwe-tẹwe ori kọmputa.
Awọn mẹtẹẹta sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun iwe yiyi, ṣiṣe ati titẹ ayederu iwe irinna ọkọ.
- Adájọ́ pàṣẹ kí wọ́n ó gbé Abba Kyari lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje ní Abuja
- Agbẹjọ́rò mi yóò tẹsẹ̀ òfin bọ ìṣẹ̀lẹ̀ Shoprite àmọ́ àwọn aláṣẹ ibùdó ìtajà náà sì ń bẹ̀ mí lọ́wọ́ - Toyin Asewo to re Mecca
- Malami ń forí ilé ẹjọ́ gba ara wọn lórí òfin ètò ìdìbò - Falana
- Ènìyàn mẹ́rin kú lásìkò tí wọ́n ń lé olè tó ja àwọn oní PoS lólè n'Ibadan
Ajọ to n pawo wọle fun ijọba ipinlẹ Kwara lo ko awọn mẹrẹrin lọ sile ẹjọ fun ẹsun naa.
Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2022, ni ajọ naa fa Bashir Alabi le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ, lẹyin ti ajọ to n fun ni ni iwe aṣẹ iwakọ lojupopo nipinlẹ Kwara, fidirẹmulẹ pe ayederu ni awọn iwe to ko wa fun silẹ fun wọn.
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa lo tẹ awọn afurasi mẹ́ta yooku, fun pe wọn n ṣe, wọn si tun n ta ayederu iwe aṣẹ iwakọ ijọba ipinlẹ Kwara.
Wọn sọ nile ẹjọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.
Eyi to mu ki adajọ ile ẹjọ naa, A.M. Ibrahim paṣẹ pe ki wọn o fi wọn si ọgba ẹwọn ijọba apapọ to wa ni Ilorin, titi igbẹjọ wọn yoo fi tẹsiwaju ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin.











