Ogun Cult Clash: Ìjọba fajúro sí ìkọlù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn

Oríṣun àwòrán, Daily post

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn

Ìfigagbága tó ń wáyé láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn níbi tí wọ́n ti ń pa ara wọn bí adìyẹ ní ìpínlẹ̀ Ogun ti tàn dé ìlú Sagamu báyìí bí ènìyàn mẹ́jọ ti ṣe pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù tí wọ́n ń ṣe síra wọn ṣe peléke si lọ́jọ́ Ajé.

Láti nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn ní àwọn afurasí bí ọmọ egbẹ òkùnkùn Ayé àti Ẹyẹ ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí ara wọn ní ìlú Abeokuta tí wọ́n sì ti ṣekúpa ènìyàn méje.

Ìròyìn ní ìkọlù náà bẹ̀rẹ̀ sí ní gbópọn nígbà tí wọn ṣekúpa ọmọ ìta kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tommy ní agbègbè Oluwo, Abeokuta, tí àwọn ènìyàn sì ti ń gbé nínú ìbẹ̀rù bojo láti ìgbà náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kòdá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Panseke, Onikolobo, Oluwo, Adigbe ti sá kúrò nílé báyìí nígbà tí ìró ìbọn kò jẹ́ kí wọ́n gbádùn nílé.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tún ṣèkọlù ní Sagamu

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn tí nawọ́ gán ènìyàn méjìdínlógún tó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó jọ wí pé ìkọlù náà ṣì ń peléke si nítorí àwọn afurasí náà ti ya wọ ìlú Sagamu báyìí, tí wọ́n sì tún ń ṣọṣẹ́.

Ní agbègbè Ajegunle, Soyindo, Ijagba, àti Sabo ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà ti ṣekúpa ènìyàn tí àwọn ará ìlú sì ti ń ké sí ìjọba láti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ọ̀rọ̀ náà.

Awoyemi Micheal, ará ìlú Sagamu tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní àláfíà ní àwọn ń fẹ́ kó jọba ní ìpínlẹ̀ Ogun àti wí pé ìkọlù gbogbo ìgbà tó máa ń wáyé láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ní ìpínlẹ̀ náà ti sú àwọn.

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń ṣiṣẹ́ láti fòpin sí àwọn ìkọlù báyìí

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, Abimbola Oyeyemi ní gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn ìpínlẹ̀ náà ni àwọn yóò fi ojú wọn wína òfin.

Oyeyemi ní àwọn ti ń ṣe gbogbo ohun tó wà ní ìkáwọ́ àwọn láti dá àláfíà padà sí ìpínlẹ̀ náà ní kíákíá.

Bákan náà ló ní gbogbo àwọn onílé tí wọ́n ń gba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn sílè ni àwọn yóò fi póró òfin gbé, tó sì rọ àwọn òbí láti ba àwọn ọmọ wọn níwọ̀ọ́ kí wọ́n yé kó ọ̀rẹ́kọ́rẹ̀ẹ́.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ogun, Dapo Abiodun náà ní olójú kò ní lajú rẹ̀ sílẹ̀ kí tàlùbọ̀ kó síbẹ̀ láéláé, wí pé àwọn kò ní gba àwọn jàǹdùkú láàyè láti da omi àláfíà ìpínlẹ̀ náà rú.

Abiodun sọ àrídájú rẹ̀ pé ìpínlẹ̀ Ogun yóò dùn gbé fún tẹrú tọmọ.

Àkọlé fídíò, Ọwọ́ mi méjèjì ni Fulani gé jábọ́, wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí n rí ìbọn gbèjà ara mi - Fijilante