Cyber Crime: Báwo ni ìyá kan ṣe rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún he nítorí ọmọ?

Debest Osarumwense

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ile ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Benin, ní ìpínlẹ̀ Edo ti sọ arábìnrin kan, Debest Osarumwense sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún.

Debest Osarumwense ni ìyá ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Endurance Osarumwense, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Yahoo boy, eyiun afurasi oníjìbìtì lórí ẹ̀rọ ayélujára.

Onídàjọ́ M. S. Shuaibu, nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ ní obìnrin náà jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án wí pé ó gba owó tó lé ní mílíọ́nù lọ́nà mọ́kànléláàdọ́rùn-ún náírà (N91m) lọ́wọ́ ọmọ náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Owó yìí ni wọ́n ní ó jẹ́ lára owó jìbìtì tí ọmọ náà lù lórí ayélujára.

Ilé ẹjọ́ wà ju obìnrin náà sẹ́wọ̀n, nígbà tí òun náà gbà pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun.

Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, EFCC ló wọ́ ìyá náà lọ sí ilé ẹjọ́ fẹ́sùn wí pé ó ń da aṣọ bo ọmọ rẹ̀ lórí lórí ìwà jìbìtì tí ó ń wù.

Debest Osarumwense

Oríṣun àwòrán, EFCC