Baba Suwe: Ọmọ olóògbé kan tàbùkù bí wọn ṣe ń pín fídíò òkú bàbá rẹ̀ kiri lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Baba Suwe
Lẹyin wakati diẹ ti gbajugbaja osere tiata nni, Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe jade laye, awuye wuye ti n su yọ lori oku rẹ.
Ni kete ti oloogbe naa mi kanlẹ, ni fidio orisi meji ti n ja rain-rain lori ayelujara eyi to se afihan oku apanilẹrin naa.
Ọjọ Aje ni agba osere tiata naa dagbere faye lasiko aisan ọlọ pipẹ to ti n ba finra.
Ki lo wa ninu fidio to n fa awuyewuye?
Ninu fidio akọkọ, ni ọkunrin apọnbeporẹ kan to pe oloogbe naa ni baba oun, ti se afihan ara rẹ ati oku Baba Suwe ni kete to ku, ti oku rẹ si la ẹnu silẹ.
Obinrin naa to di ori oku Baba Suwe mu lo n fi omije sọrọ pe baba oun ti lọ.
Ọkunrin naa ni "Ko si ẹbi, ko si ara, a pe wọn lootọ amọ ko si ẹbi. Baba mi ti lọ, mo maa n nifẹ ọkunrin yii ni gbogbo igba, ẹyin ẹbi mo dupẹ o, ẹ seun o, amọ n ko ni sọ ju bayii lọ."
Fidio keji naa lo fi ara pẹ ti akọkọ, ninu fidio naa si ni wọn ti se afihan oku Baba Suwe lati ori de isalẹ.
Oloogbe naa lo sun sori ibusun, o la ẹnu silẹ, ti oju ibi ti wọn lẹ pilasita si wa ni apa mejeeji rẹ.
Baba Suwe lo wọ asọ ankara olomi buluu eyi to wọ titi to fi mi kanlẹ, to si sun silẹ laimira bi o tilẹ jẹ pe fidio naa ko ni ohun.
Ninu fido naa si lo ti foju han pe Baba Suwe ti ru pupọ ko to jade laye, to si yatọ si Baba Suwe to ni omi lara, eyi ti gbogbo aye mọ.
Ọpọ eeyan lo ti n sọ ero ọkan wọn lori awọn fidio mejeeji naa, eyi to n tabuku oloogbe, ti wn si n bu ẹnu atẹ lu ẹni to wa nidi bi fidio naa se de ori ayelujara.
Ọmọ Baba Suwe miran tako afihan fidio oku baba rẹ:
Boya ariwisi awọ̀n araalu yii lo mu ki ẹlomiran, to jẹ ọmọ oloogbe naa, Adesola Omidina se kede loju opo ayelujara rẹ lati tako igbesẹ afihan oku baba rẹ lori ayelujara.
Ọmọ Omidina @ omo_omidina loju opo Instagram, lo fi atẹjade kan sita pe oun n fi gbogbo ẹnu tabuku awọn fidio mejeeji naa.
O ni awọ̀n fidio to n se afihan oku baba oun lawọn oju opo ayelujara ni ko tọna bi wọn se gbe jade rara.
Bakan naa lo sẹ lori ẹsun pe awọn ko ri oluranlọwọ kankan lati se itọju oloogbe naa lasiko to wa lori ibusun aisan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Afurasí ológun gbé alága NURTW tẹ́lẹ̀ l‘Oyo pé ó ń ṣe onígbọ̀wọ́ Sunday Igboho
- Bí Buhari bá fi Sunday Igboho sílẹ̀, ìṣọ̀kan yóò padà sí Naijiria - Oluwo
- "Àgbà Yorùbá dalẹ̀ Sunday Igboho, wọ́n fi sílẹ̀ bíi ọmọ òrukàn"
- Àìsí Atúmọ̀ èdè Yorùbá sí Gẹ̀ẹ́sì pagidínà ìgbẹ́jọ́ ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho méjì
- Naijiria yóò dojúrú tí Buhari bá tú Nnamdi Kanu sílẹ̀ - Ẹgbẹ́ àpapọ̀ l‘Ókè Ọya
- "Buhari, Sanwo-Olu, ẹ kọ̀wé fipò sílẹ̀ torí àwọn ọ̀dọ́ tó kú lásìkò ìwọ́de EndSARS"
- Ìjọba Eko fi ọwọ́ ọlà gbá ìyá Jumoke lójú ní ₦1m àti ilé tó hááyà fún - Agbẹjọ́rò
O ni ẹgbẹ awọn osere tiata, TAMPAN, ijọba, awọn wolii, ẹbi ati ololufẹ baba oun ni wọn sugba awọn niwọnba bi agbara wọn ti mọ, ti wọn si se iwọn ti wọn le se.
Adesola Omidina wa lo anfaani ikede naa lati tọrọ aforijin lọwọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ, awọn eeyan ati ẹbi wọn.
Ọmọ Baba Suwe naa wa n rọ awọn araalu lati kọ ẹyin si awọn fidio ti ko tọna naa, eyi to ti lu ori ayelujara pa.

Oríṣun àwòrán, omo_omidina/Instagram
Ọjọbọ ni a sin oku Baba Suwe:
Nibayii na, ikede ti jade lori eto isinku Baba Suwe.
Atẹjade miran ti ọmọ oloogbe, Adesola Omidina fisita loju opo Instagram rẹ ni aarọ ọjọ Isẹgun kede pe Ọjọbọ ni wọn yoo gbe oku oloogbe naa wọ kaa ilẹ.
Atẹjade naa ni ile oloogbe to wa ladupo Elepe nilu Ikorodu ni wọn yoo ti sin Baba Suwe ni deede aago mẹwa owurọ.
Adesola Omidina ni awọn mọlẹbi oloogbe yoo kede ayẹyẹ isinku nigba to ba ya.
Ọjọ Aje, ọjọ Kejilelogun osu Kọkanla ọdun 2021 ni agba osere tiata naa, tii tun se adẹrinposonu ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe ki aye pe o digbose.
Ọdun mẹtalelọgọta ni alawada naa lo loke eepẹ, ko to dagbere faye lasiko aisan ọlọjọ pipẹ to ba finra.

Oríṣun àwòrán, omo_omidina/Instagram















