Baba Suwe: Ilé iṣẹ́ aṣọ́bodè kò fún bàbá mi ní kọ́bọ̀, igbákejì Ààrẹ kàn tọrọ àforíjìn ni - Ọmọ Bàbá Sùwé

Oríṣun àwòrán, Bababsuwe/ instagram
Ọpọ eniyan lo ti n ṣe aaro ilumọọka adẹrinposonu nni, Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe nitori bi oju rẹ ṣe sọwọn lasiko yii ninu ọpọ ere sinima.
Eyi ko si sẹyin aisan ara to ṣee laipẹ yii, to mu ki wọn gbee lọ soke okun fun itọju pẹlu atilẹyin awọn ẹlẹyinju aanu ọmọ Naijiria kan.
Bi awọn ọmọ Naijiria si ṣe n poungbẹ adẹrinposonu naa, lo mu ka fi ọrọ wa Baba Suwe lẹnu wo, ki ọkan araalu le balẹ pe, alaafia ni baba wa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Baba Suwe ti ohun rẹ ko fi bẹẹ ja gaara ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o da ẹmi oun si ninu ipenija ara ti oun la kọja.
O salaye pe ẹgbẹ osere TANPAN duro ti oun lasiko ti oun ṣe aisan, to fi de ori awọn alagbata sinima ati ọpọ eeyan miran, ko to di pe Ọlọrun la oun.
Baba Suwe, ẹni to ranti iku aya rẹ, Mọladun Kẹnkẹlẹwu, to jẹ gbajumọ oṣere tiata miran nigba aye rẹ, lasiko ifọrọwerọ naa wa fajuro pe, oun mọ iku iyawo oun naa lara, ti oun si n ṣe aaro rẹ ni ojoojumọ.

Oríṣun àwòrán, @Austynzogs
Baba Suwe ni "n ko tii ni iyawo miran tabi ọrẹbinrin kankan rara lẹyin iku Moladun aya mi titi di akoko yii, kii si ṣe pe o wu emi naa lati da duro."
Nigba to n sọrọ lori aheso ọrọ kan to ni Baba Suwe lo lu iyawo rẹ titi ti onitọun fi jade laye,
Baba Suwe ni eyi ko ri bẹẹ rara nitori ko si ija abi ita ni aarin awọn, oun ko si lọwọ ninu iku obinrin naa.
Lori oju to fi wo ipo ti awada ṣiṣe ninu ere tiata de duro lode oni, adẹrinposonu naa tun woye pe, ọpọ awọn eeyan to n ṣe awada lasiko yii ni wọn n ṣe gudugudu meje ati ya ya mẹfa nitori ko rọrun lati pa awọn eeyan ni ẹrin.
"Emi gan an ti ni ọmọ to n ṣe awada lagbo iṣẹ tiata, orukọ rẹ si ni Olusola Omidina.
Nigba toun naa bẹrẹ si i ba BBC Yoruba sọrọ, Olusola ọmọ baba Suwe ni, aṣeyọri ti baba oun ṣe ninu isẹ tiata lo ṣe iwuri fun oun, lati dara pọ mọ awọn oṣere tiata.
Olusola, ẹni to kọ ẹkọ nipa sinima ṣiṣe nilẹ Amẹrika fikun un pe, ọpọ ipenija ni oun n koju nidii isẹ naa, ti awọn osere yoku kii si fẹ pe oun lati wa ṣiṣẹ pẹlu wọn.
Nigba to n sọrọ lori aisan to n ṣe Baba rẹ, Olusola ni "nkan ko fi bẹẹ dabi mọ fun baba mi nitori oju apa ko jọ oju ara fun un, bi aisan naa si ṣe n lọ, lo tun n pada, ti ọrọ naa ko si ye mi mọ rara."
Olusola wa gba ẹnikẹni to ba nifẹ si ere tiata nimọran pe onitọhun gbọdọ kawe bo ṣe yẹ, ko ni suuru, ko ma si tori owo se iṣẹ ọhun, nitori iṣẹ tiata ko ni owo gidi lori.
Bẹẹ ba gbagbe, ileesẹ aṣọbode nilẹ wa gbe Baba Suwe si ahamọ lọjọ kẹrinla, oṣu kẹwaa, ọdun 2011, eyiun ọdun mẹsan an sẹyin lori ẹsun pe o gbe oogun oloro.
Ọrọ naa di tile ẹjọ, ti Baba Suwe si jare bo tile ẹjọ si ni ki Ileesẹ aṣọbode san ẹgbẹrun lọna ọgọrun un pọun fun un, gẹgẹ bii owo 'gba ma binu'.
Nigba to n fi idi rẹ mulẹ boya baba rẹ ti ri owo naa gba lọwọ Ileesẹ aṣọbode, Olusola ni Ileesẹ aṣọbode nilẹ wa ko fun baba oun ni kọbọ ninu owo tile ẹjọ ni ki wọn san fun baba oun, lori iya ti wọn fi jẹ ẹ ní ahamọ.
Amọ ko sai yan ọrọ rẹ pe, "igbakeji aarẹ, ni orukọ ijọba apapọ, ti tọrọ aforijin lọwọ baba mi lori iṣẹlẹ naa, ti a si ti fi ija fun Ọlọrun ja, fọwọ lẹran."
O ni iku agbẹjọrọ to n ba baba oun ṣe ẹjọ ifiyajẹni lọna aitọ naa, Bamidele Aturu, lo mu akude nla ba igbesẹ gbigba owo naa.
"Ṣugbọn a ti gba kamu nitori owo tile ẹjọ ni ki Ileesẹ aṣọbode san fun baba mi gan an kere, si iye owo to fi tọju ara rẹ fun aisan loke okun."
Nollywood: Baba Suwe, Baba Wande àtàwọn òṣèré apanilẹ́rìn ín Yorùbá wọ̀nyí dà?

Oríṣun àwòrán, Baba wande/aluwe/Elẹṣọ/baba suwe/ suwe/ Inst
Ere sinima agbelewo ede Yoruba ti gbẹrẹgẹjigẹ di igi alọye, ti owo rẹ si ti to ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira bayii.
Sugbọn lara awọn osere to gbe ẹka amuludun naa de ipo nla to wa loni, ni awọn adẹrinpoṣonu ti wọn wa lasiko ipilẹ sinima Yoruba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ko si ani-ani pe, Yoruba lo pilẹ ere sinima agbelewo lorilẹede Naijiria, ti awọn agba oṣere Yoruba bii, Hubert Ogunde, Iṣọla Ogunṣọla, Ogunmọla, Ade Afọlayan, Adelove, Baba sala ati bẹẹbẹẹ si gbe ere itage de ibi to ga.
Lẹyin eyi ni Muyideen Aromirẹ gbe sinima agbelewo akọkọ, to pe akọle rẹ ni 'Ẹkun' jade ni ọdun 1988.
Ohun kan pataki ti awọn sinima bii Aṣiri nla, Ti Oluwa nilẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ lo lati fi fa oju awọn eeyan mọra lasiko naa ni lilo awọn adẹrinpoṣonu ninu awọn sinima wọn nigba naa.
Eyi ni akojọpọ awọn adẹrinpoṣonu ti wọn ti logba ni agbo sinima ni ilẹ Yoruba, amọ ti oju wọn ko fi bẹẹ se deede mọ ninu awọn fiimu agbelewo.
Baba Suwe:
Gbajugbaja ati ilumọọka apanilẹ́rìn ín ni Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si 'baba suwe' lagbo adẹrinpoṣonu ninu sinima ni ilẹ Yoruba. O si jẹ orukọ kan to lọ fun ọpọ ọdun.
Ni ipilẹ sinima ni ilẹ Yoruba, gbogbo awọn onworan ni igba naa ni wọn maa n foju wa arakunrin rọgbọdọ aboju dudu họhọhọ pẹlu ṣokoto ti o tobi juu lọ, ti o fi okun ẹran nla so pẹlu ẹwu agbotutu lọrun.
Ko si ile ti ko fẹrẹ mọ Baba Suwe ni igba naa.
Ọdun 1958 ni wọn bi Babatunde Omidina, ti ọpọ mọ si Baba Suwe ni ilu Eko.
Ni ọdun 1972 ni Baba Suwe di osere tiata sugbọn sinima Ọbalende lo gbe orukọ rẹ jade. Bakan naa ni awọn sinima bii Iru ẹsin, Baba jayejaye ati ọpọ sinima miran tun gbe orukọ rẹ jade.
Lẹnu lọwọlọwọ yii, oju gbajugbaja adẹrinpoṣonu yii ko fi bẹẹ han mọ ninu sinima.
Aluwẹ, ọmọ iya Alaro:

Oríṣun àwòrán, Aluwe/instagram
Ṣaṣa ni awọn ti o mọ ipilẹ ere sinima ede Yoruba, ti ko mọ nipa Sunday Ọmọbọlanle ti ọpọ eeyan mọ si Aluwẹ tabi Papi Luwẹ.
"Baba Mero, Ọga mi lo fun ni orukọ Aluwẹ ti mo n jẹ ninu ere, ṣugbọn agba olorin, Sunny Ade lo fi Papiluwẹ kun un."
Ilu Ilọra ni ipinlẹ Ọyọ, ni wọn bi Aluwẹ si ni ọdun 1954. Lati aye ere ori itage wọ sinima onifọnran celulloid ni Aluwẹ ti n da bira.
Nitori ipa ti o ko ninu ẹka amuludun lorilẹede Naijiria, ni ijọba apapọ se fi ami ẹyẹ orilẹede Naijiria, MON daa lọla.
Lori mohunmaworan akọkọ nilẹ wa, to wa nilu Ibadan, (NTA Ibadan) ni orukọ Aluwẹ ti kọkọ gbalẹ kan, nigba to n sere Awada Kẹrikẹri pẹlu ọga rẹ, baba Mero ati Adebayọ Salami, ta mọ si ọga Bello.
Nigba to ya ni oju rẹ di gbjumọ ninu awọn ere sinima bii, Adun Ewuro, Konkobilo, Oba Alatise ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Opẹbẹ:

Oríṣun àwòrán, Miliki express
Yọmi King ni orukọ abisọ rẹ ṣugbọn Ọpọbẹ ni orukọ ti ọpọ eeyan mọọ si gẹgẹ bii orukọ ti o maa n jẹ ninu awọn sinima.
Ẹyẹ meji kii jẹ aṣa ni ọrọ Ọpẹbẹ ninu sinima nitori oun naa ni oṣere apanilẹrin ti o maa n gbe iwa akanda ẹda ti ọwọ n dun wọ, ninu sinima Yoruba.
Ọmọ ipinlẹ Ogun ni, ere ọlọsọọsẹ ori mohunmaworan ti wọn n pe ni 'Ẹrin keeke' ni o gbe Ọpẹbẹ saye ni ọdun 1987 lori ikanni mọhunmaworan Channel 8.
Ọpọ ere ti baba Suwe ba ti kopa, naa ni Ọpọbẹ maa saba n kopa ninu rẹ.
Ẹlẹṣọ ẹnu n ja waya:

Oríṣun àwòrán, Eleso adewale/ facebook
Afin to da yatọ ninu sinima ni Adewale Ẹlẹṣọ, ti ọpọ mọ si Ẹlẹṣọ ẹnu n jawaya. Nitori awọn ọrọ nlanla ti o maa n sọ ninu sinima, lo faa ti awọn eeyan fi n pee ni orukọ yii.
Iṣẹ nọọsi, iyẹn olutọju alaisan ni ẹlẹṣọ n ṣe ki o to di elere itage.
Ohun ti o da Ẹlẹsọ yatọ si awọn adẹrinpoṣonu yoku ni ọrọ kabiti ẹnu rẹ ti ko lee ṣai dẹrin pẹrẹkẹ eniyan to ba wo sinima ti o ba wa.
Amọ oju tiẹ gan ko fi bẹẹ se deede mọ ninu ere tiata.
Dẹjọ Tunfulu:

Oríṣun àwòrán, Dejo tunfulu
Ọkan lara awọn apanilẹrin to gbajugbaja ni ipele sinima agbelewo ede Yoruba ni Kunle Makinde Tokunbọ ti ọpọ mọ si Dẹjọ Tunfulu.
Agbegbe Idumọta ni ilu Eko ni wọn bi Dẹjọ tunfulu si ni ọdun 1969, ṣugbọn ọmọ ilu Abẹokuta ni.
Ohun ẹnu rẹ ti o dabi ti ọmọde ni o da Dẹjọ yatọ laarin awọn adẹrinpoṣonu yooku. Ohun yii gan ni o fa orukọ 'tunfulu' ti wọn n pe e ninu awọn sinimọ ti o ti kopa.
"Ọdun 1987 ni mo ti bẹrẹ si nii ṣe ere itage. Mo si maa nkopa ninu 'Tiata Ọmọde' lori ikanni Channel 7 mohumaworan apapọ ilẹ Naijiria, NTA ."
Dẹjọ ti kopa ninu awọn sinima bii Tori ife, Aya rere, Owo o mo agọ, Born boy, Ẹrọ ibanisọrọ, Ejide, Itọ, adigun ati bẹẹbẹẹ lọ.
Baba Wande:

Oríṣun àwòrán, Babawande/instagram
Ara awọn agba ọjẹ ere sinima ede Yoruba ni Alhaji Kareem Adepọju, ti ọpọ mọ si 'Baba Wande' , o si ti lo to ọdun marunlelaadọta ninu ere itage ati sinima.
Ẹgbẹ Oṣere oloogbe alagba Oyin Adejọbi ni baba wande ba ṣiṣẹ pọ fun ọpọlọpọ ọdun, ṣugbọn ninu ere 'Ti Oluwa ni ilẹ’ ti o jade ni ọdun 1993 ni Baba Wande ti di gbajugbaja ni Naijiria titi de oke okun.
Ipa 'oloye Ọtun' ti o ta ilẹ oriṣa ninu sinima naa, si ni baba Wande se.
Awọn sinima bii Ti oluwa ni ile (1993), Obukọ Dudu, Ẹkun Ọkọ Oke, Ayọ ni mo fẹ (1994), Nkan asiri (2005), Oyatọ (2002) Obinrin Sọwanu(2004), Aya mi ọwọn: Madam Dearest (2005) Durodọla (2005) Atanpako ọtun (2007) ati bẹẹbẹẹ lọ ni diẹ lara awọn iṣẹ ti Baba wande ti ṣe.
Sugbọn nibo ni Baba Wande wa lasiko yii ninu ere tiata, gẹgẹ bii awọn yoku ti a ti mẹnuba saaju?















