Dejo Tunfulu: Ẹ wo bí Dejo Tunfulu tó dágbéré fún ayé ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òṣèré...

Dejo Tunfulu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ibanujẹ ọkan lo jẹ fun awọn ololufẹ gbajugbaja oṣere ti gbogbo eniyan mọ gẹgẹ bi adẹrinpoṣonu, Dejo Tunfulu lẹyin ti iroyin iku rẹ bọ si ori ẹrọ ayelujara.

Dejo Tunfulu naa lo dagbere fun aye naa ni ọpọlọpọ ko mọ bi o ṣe bẹrẹ irinajo rẹ gẹgẹ bi oṣere.

Dejo Tunfulu

Nigba taa bere ohun ti ọpọ eeyan fẹ mọ boya o ṣi n ri owo ninu iṣẹ rẹ, ṣe lo n yi ibeere wa ti ko fẹ sọrọ nipa awọn akẹgbẹ rẹ rara.

Nígbà tí a fọ̀rọ̀ wá olóògbé Dejo Tunfulu lẹ́nu wo lórí Facebook wa, ṣe ni kò fẹ́ mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ bóyá àwọn akẹ́gbẹ́ wọ́n máà ń pa ẹni tí kò bá ri ṣe mọ́ tì.

"Ninu iṣẹ Tiata wa yii, ṣe ẹ mọ pe eeyan ti pọ nibẹ, iru awa bayii a kan ti wa bakan ni lasiko yii amọ emi naa gbe fiimu kan jade bayii".

O ni ṣe toripe oun jẹ Dejo, oun a ni ki awọn mii ma ṣe ipa ẹfẹ ninu ere ni.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe ló wá ra epo níbi tí mo ti ń di "nussle" epo mú mo bá bẹ́ mọ́ ọ́, bí ayé mi ṣe yí padà di òṣèré fíìmù rèé

Dejo ṣalaye pe ti wọn ba kọkọ da nkan silẹ, awọn kan lo maa n kọkọ duro ti nkan yẹn amọ to ba ya ero maa pọ awọn kan a si maa sun sẹyin.

O ṣalaye pe o da bii ọti ẹlẹrindodo ti ko ju bii meji lọ nigba ti wọn ṣẹṣẹ ṣe e jade amọ o ti pọ bayii eyi to ba si wu eeyan lo maa ra. "Ẹnikan kii jẹ ki ilẹ fẹ.

Mo fun awọn to jade lẹyin mi laaye ni ki awọn naa ko ipa ninu ere pẹlu ẹbun ti Eleduwa fun wọn".

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Àkọlé fídíò, Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba ni Tunfulu ti salaye bi o ti ṣe bẹrẹ si ni ṣe sinima lati ọmọ kekere.

O ni ileewe girama ni oun wa ti oun fi bẹrẹ iṣẹ oṣere. ti oun si ti fẹran iṣẹ osere nitori Yinka Quadri n gbe ni adugbo wọn ti awọn si ma lọ n yọju wo wọn lasiko ti wọn ba n ṣe sinima lọwọ.

''Ati kekere ni mo ti n se fiimu nitori mo fẹran bi mo ṣe ma n ri awọn eekan ninu iṣẹ oṣere ati ipa ti wọn kọ ni iṣẹ oṣere''

'' Idumota ni wọn bi mi si amọ Ilu Abeokuta ni mo ti ṣẹ wa, nkan bi ọgbọn ọdun ṣẹyin ni mo bẹrẹ iṣẹ oṣere''

''Awọn ti mo wo gẹgẹ bi akọṣe nigba naa ni Yinka Quadri nitori wọn n ta ọja ni agbegbe Dosunmu nipinlẹ Eko nibi ti a n gbe.''

Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

''Ninu fiimu ti mo kọkọ kopa pato ni wọn ti safihan emi ati aburo mi to jẹ akanda ẹda ti wọn bi ni ọjọ kan, to rin ni ọjọ kan , to si sọrọ ni ọjọ kan naa.''

''Amọ nitori kii ṣe ọjọ ti wn ba bi ọmọ ni wọn ma n sọ lorukọ ni mọ ṣe ma n pe aburo mi naa ni Tunfulu,ti awọn ololufẹ wa ko ba si ri wa ninu fiimu ni wọn ma n bere pe Dejo Tunfulu.''

Bakan naa lo fikun un pe idi ti oun ko fi kọpa ninu sinima bii ti tẹlẹ ni pe awọn eniyan ko ra fiimu mọ bii ti tẹle niṣe ni wọn ma n lọ si ori ayelujara lati lọ wo fiimu, eleyii to ma n ko ipalara ba awọn oṣere nitori wọn n kuna ọpọlọpọ owo ti wọn ti na lori gbigbe sinima naa jade.

Nigba ti wọn beere pe ṣe alafia ni oun, iyawo ati ọmọ wa, Dejo ni "bẹẹ ni alafia la wa". Amọ lẹyin iku rẹ ni iroyin jade pe oun nikan lo tọju awọn ọmọ rẹ dagba toripe iya wọn fi wọn silẹ lọ.

Dejo ati Baba Suwe

Oríṣun àwòrán, Instagram/ dejomania

Wo àsọtẹ́lẹ̀ tí Dejo Tunfulu tí sọ ṣáájú nípa irú iku tó lè pa

Dejo Tunfulu jẹ oṣere kan to kọ orisi iha si oniruuru eeyan nigba to wa laye.

Nibayi to ti wọ kaa ilẹ lọ, apejuwe lorisirisi lawọn eeyan to mọ adẹrinposonu naa n sọ nipa rẹ.

Fawọn ololufẹ rẹ lagbo ere tiata, oninu rere ni, ti o si ma n dẹrin pẹkẹ araalu.

Àkọlé fídíò, Seye Malaolu: Bí mo ṣe rí àgbára ẹ̀jẹ̀ tó kúnlẹ̀, mò ń bèrè pé ṣé wọ́n pa Turkey níbí ni,
Àkọlé fídíò, 'Ojú mi méjèjì pé lọ sí ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá SARS, bí mo ṣe di afọ́jú ọ̀sàn gangan lórí ẹ̀sùn jíjí pọ́ọ̀sì “customer” tí mi ò mọ

Yatọ si eleyi, o tun jẹ onwoye ti ọpọ ọrọ rẹ a si maa kun fun ọgbọn bo tilẹ jẹ pe ipa didinrin lo maa n ko ninu ere sinima.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Láti kékeré mo ti ní ọjọ́ kan lèmi náà ọ́ kọ́ Mọ́sálásí kékeré bíi àwọn bàbá wa'

Apẹrẹ kan taa ri nipa ọgbọn ati oye ti gbajugbaja apanilẹrin yii ni farahan ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu oju opo Ojopagogo TV lori Youtube.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo taa n wi yii, Dejo Tunfulu sọrọ nipa iku ti yoo pa, to si woye nipa ọjọ ti inu rẹ dun julọ laye.

Àkọlé fídíò, Babatunde Adejumo: Ọdún méje ní mi fi sá kúrò nídìí iṣẹ́ aṣerunlọ́sọ̀ọ́ àmọ́ mo padà

Ni idahun si ibeere ẹlẹẹkeji nipa igba ti inu rẹ dun julọ nigba to wa laye, niṣe ni Dejo rẹrin musẹ to si dahun bayi:

''Mi o le sọ igba ti inu mi dun julọ laye ayafi ti mo ba ku tan.''

O tẹsiwaju pe ''Igba ti mo ba ku tan, lẹ le wa ba mi pe ọgbẹni Dẹjọ, igba wo ni inu rẹ dun julọ nigba to wa laye?''

Idahun rẹ yii ṣafihan iwoye rẹ, to ni si pe eeyan ko le sọ pato pe ọjọ bayi ni inu oun dun julọ nitori ọjọ mii tun le wa, ti nkan idunnu to ju ti tẹlẹ yoo waye.

Àkọlé fídíò, BBC Africa Eye díbọ́n bíi ọmọ ìjọ, àṣírí àwọn Pásítọ̀ èké nílẹ̀ yìí tú sí wa lọ́wọ́

Kò sí súgà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìrìnajò òun, ó korò bíi ewúrò ni - Dejo Tunfulu

O ti to nkan bi ọdun mẹrindinlogoji si marundinlogoji ti Dejo Tunfulu ti orukọ rẹ gangan njẹ Adekunle Makinde Adetokunbo ti bẹrẹ ere tiata.

Ninu alaye to ṣe fun OjoPagogo Tv, Dejo Tunfulu sọ pe lati ara gbajumọ osere binrin Fausat Balogun, ti ọpọ eeyan mọ si Madam Sajẹ ati ọkọ rẹ ni oun dide lara wọn nidi isẹ tiata.

O tẹsiwaju pe oun koju orisirisi ipenija ati pe o ni "ko si ṣuga ni ibẹrẹ irinajo mi', o koro bi ewuro ni, to si kan bi omi ogi' lati bii ọdun mẹrindinlogoji, ti oun ti bẹrẹ isẹ naa.

Amọ o wa dupẹ lọwọ Ọlọrun pe oun papa ri taje se nidi isẹ naa, ti oun si fi ran ọmọ lọ sile ẹkọ.

Aworan Dejo Tunfulu

Oríṣun àwòrán, Instagram/ dejomania

Dejo Tunfulu sọ asọtẹlẹ nipa iku rẹ:

Nigba ti wọn beere lọwọ Dejo nipa iku, o fesi pada pe ''ẹni ti ko ti ku, ko le sọ iru iku to maa pa''

Dejo ṣalaye pe nipa adura tawọn eeyan maa n se pe ki eledua jẹ ki iku rere pa wa, o di igba ti eeyan ba ku tan ko to le mọ iru iku to pa.

''Ẹ le beere boya iku rere lo pa mi bi mo ba ku tan'' esi to fi pari ọrọ nipa iku ree.

Dejo wa ni oun ko tii de ibi ti oun n lọ, afi ki Ọlọrun mu oun de ibẹ.

Awọn to mọ Dejo jẹri si pe kii ṣe ẹni to wa aye mọya, ti o si kun fun iwa irẹlẹ.

Mo rin lati Ado-Ekiti de idaji Ondo:

Nigba to n salaye ọpọ ipenija to ti koju rẹ sẹyin lagbo tiata ninu ifọrọwanilẹnuwo naa, Dejo Tunfulu ni ipenija ti pọ ju.

O ni awọn iriri to mu omi loju oun ti pọ pupọ ju, to si mẹnuba akoko kan ti wọn lọ fun ere sise alagbeka lọ silu Ado Ekiti.

"N jẹ ẹ le gbagbọ pe lati ilu Ado-Ekiti, ki eeyan si rin de idaji Ondo nigba ti ko si owo ounjẹ, ti ko si si nkankan.

Sugbọn ti eeyan ba ti fori ti nnkan, yoo dara to ba ya, mo si dupẹ pe Ọlọrun ko jẹ ki n di ero ẹyin."

Àkọlé fídíò, Omi Adio Robbery: Èèyàn márùn-ún tí kò mọwọ́-mẹsẹ̀ ló kú lásìkò ìdigunjalè PoS l‘Omi Adio

Nibo lo ti ri orukọ Dejo Tunfulu?

Dejo Tunfulu sisọ loju ibi to ti se alabapade orukọ to n jẹ ninu ere tiata, eyiun Dejo Tunfulu lori eto naa.

O ni nigba ti oun kere ninu isẹ tiata, ọga oun kan to n jẹ Lagelu Akinbola lo wa pe oun ninu ẹgbẹ osere ti oun wa, eyiun Akukọ Gagara Theatre Group, lati wa ba kopa ninu ere kan ni National Theatre nilu Eko.

O ni ninu ere naa, wọn n pe oun ni Dejo, ti oun si jẹ ẹgbọn ọmọ tuntun abami kan ti wọn bi, to sọrọ, to jẹun, to si rin lọjọ ti wọn bi.

O ni oun wa maa n pe ọmọ tuntun abami naa ni Atunfulu, ti awọn ololufẹ oun si gba ibẹ sọ oun ni Dejo Atunfulu tabi Dejo Tunfulu.

Ta ni Dejo Tunfulu:

Kunle Makinde Adetokunbo, ti ọpọ eeyan mọ si Dejo Tunfulu lo jẹ gbajumọ adẹrinposonu nigba aye rẹ.

Ọjọ Ẹti, ọjọ Kinni osu Kẹrin ọdun 2022 ni Dejo Tunfulu mi kanlẹ sile iwosan kan ladugbo Ikorodu lasiko aisan ranpẹ.

Aadọta ọdun ni loogbe naa lo loke eepẹ, ki ọlọjọ to de.

Ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún, ọdún 1972 ni wọ́n bi Tunfulu ní Idumota, Lagos Island, nipínlẹ̀ Eko.

Ọmọ bíbí ìlú Ikija, Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun ni.

Dejo Tunfulu lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní Ansar-Ud-Deen, Lagos Island, lẹ́yìn èyí ló lọ sí Modern Way Nigeria School of Printing níbi tó ti gbàwé ẹ̀rí nípa ìmọ̀ ìtẹ̀wé.

Ipa adẹ́rìnínpòṣónú ló máa ń kó nínú eré sinimá tó sì máa ń kálòlò nínú eré.

Sinimá Omo Oran ló fi di gbajúgbajà èyí tí òun àti Lalude jọ ṣe.

Ní ọdún 1987 ló kọ́kọ́ ṣeré lórí amóhùnmáwòrán nígbà tó kópa nínú eré ọlọ́sọ̀ọ̀ṣẹ̀ Apere Ijogbon èyí tí ikọ̀ Kolawole International Theatre Group máa ń gbé jáde.

Ní ọdún 2012 ló pàdánù ìyàwó rẹ̀ tó kọ́kọ́ fẹ́ sọ́wọ́ ikú.

A wa n gbadura pe ki Ọba Oke tẹ gbogbo wọn si afẹfẹ rere.

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta