New Soun of Ogbomoso: Fàá-kín-n-fàá lórí fífá olùdíje ipò Ṣọun sílẹ̀ ń wáyé ní igun oyè Laoye, wo ohun tí àwọn mọ̀lẹ́bí ilé Arẹmo ń wí

Ọrọ oye ipo Soun Ogbomoso ti tun gba ọna miran yọ lẹyin ti ọkan ninu awọn idile to n du ipo naa ni awọn afọbajẹ yọ ọwọ ọmọ wọn lawo lati le fi dije ipo Soun.
Idile Adajọ Mofoye Oyetunde Ile Aremo, lo fidi ọrọ yi mulẹ fun ileeṣẹ iwe iroyin Naijiria Punch ninu ifọrọwerọ.
Ileeṣẹ iroyin yi jabọ pe ọkan lara awọn mọlẹbi to ni ibatan loun jẹ si ọmọ ọba Oyebode Oyetunde to fẹ du ipo Soun ni idile Aremo lo gbẹnu mọlẹbi sọrọ.
Dokita Usman Akano ni Oyetunde kaju oṣunwọn lati gun ori oye lẹyin ti Soun ti tẹlẹ Oba Oladunni Oyewumi waja ni ọjọ Kejila oṣu Kejila 2021.
O ni ''ọmọ ọba ni Oyebode Oyetunde lati idile Aremo to jẹ idile ti wọn ti n jọba ni igun Laoye amọ wọn ko jẹ ki o dije toun ti pe wọn mọ pe idile Aremo lokan lati fa Soun mii kalẹ''
O kesi Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ati awọn alaṣẹ ijọba ibilẹ lati ri pe wọn tẹle ilana to de yiyan Soun ki wọn si ma yọ ọwọ ọmọ ọba kankan lawo.
Tori naa o ni ''ki Gomina Seyi Makinde paṣẹ ki wọn tun eto yiyan ọba naa bẹrẹ pada ki wọn si ri pe wọn ko yapa lori ilana ki aawọ baa ma ṣẹlẹ''
Ninu alaye ti Dr Akano ṣe, o ni wọn kọdi Oyebode lati ri fọọmu idije fun ipo Soun gba ni.
''Nigba ti Oyebode Oyetunde beere fọọmu, wọn ni eto ti pari. Eleyi ko bojumu rara.''
O naka si Alhaji Wahab Oyetunde lati idile ọlọba Laoye gẹgẹ bi ẹni to sọ fun ọga ileeṣẹ ifowopamọ idagbasoke Africa naa pe wọn ti gba fọọmu tan.
Amọ Akano ni lẹyinigba ti wọn ni ko si fọọmu mọ yi ni wọn tun taa fun awọn oludije miran to wa lẹyin Oyetunde.
Lafikun, o ni ohun tawọn n tako ni ọna ti ko tọ ti wọn fi ṣeto yiyan awọn oludije.O tẹsiwaju pe awọn afọbajẹ ko tẹle ohun ti ofin sọ.
''Ohun ti ofin sọ ni pe orukọ kan ṣoṣo lo yẹ ki wọn fi ranṣẹ lati idile to n jẹ oye lọ si ọdọ awọn afọbajẹ ṣugbọn nkan ti wọn ṣe kọ ni yẹn''
''Bo ti lẹ jẹ wipe a ko fẹ ṣẹjọ lori ọrọ yi, a ko fẹ ki ọrọ de ibẹyẹn. A fẹ yanju rẹ ni tubi n nubi ni.''
''Awọn ijọba ibilẹ ati ipinlẹ gbọdọ ri pe wọn tẹle ofin ki wọn si maa gbegi dina eeyan kankan.''
O ni ofin to de yiyan ọba Soun ọdun 1957 fi lelẹ pe oludije kan pere ni wọn gbọdọ fi ranṣẹ si awọn afọbajẹ fun iwadii ati ayẹwo finifini.
O ni bi ẹni yi ko ba tẹ wọn lọrun, wọn lẹtọ lati da pada ki wn tun fi orukọ ẹlomiran ranṣẹ si awọn afọbajẹ lati ọdọ idile to n jẹ ọba yi.














