Chinyere: Ṣé lóòótọ́ ní pé ọkọ arábìnrin yìí torí ogún dáná sún òun àti àbúrò rẹ̀ láàyè?

Oríṣun àwòrán, Chinyere Ogudoro
Ojumọ kan iroyin kayefi kan.
Eleyi taa mu tọ yin wa lati ipinlẹ Eko yoo gba ki ẹ fi ẹlẹ ka a ki ẹ si wa nkan fidi le.
Ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti mu arakunrin kan lori ẹsun pe o dana sun iyawo rẹ laaye.
Igbeyawo tọkọtaya yii ti wọ nkan bi ọdun mẹwaa ti wọn ti n baa bọ.
Ọkọ iyawo yi taa gbọ pe ọjọ ori rẹ ti wọ aadọta ọdun ko dana sun iyawo nikan. Ana rẹ lọkunrin naa kan agbako didana sun un pẹlu.
Lọjọ keji iṣẹlẹ yi lawọn ọlọpaa mu arakunrin naa nigba ti inu ti n bi awọn araadugbo to gbọ nipa iṣẹlẹ yi.
Iyawo rẹ, arabinrin Chinyere Ogudoro taa gbọ pe o ṣẹṣẹ dari lati orileede Scotland lo kọkọ ku sinu ina.
Aburo rẹ lọkunrin de ile iwosan ki o to gbẹmi mi gẹgẹ bi mọlẹbi wọn kan ṣe sọ.
Awọn ọmọ iya meji yi jẹ meji ninu ọmọ marun un tawọn obi wọn bi.
Ẹni ọdun mejidinlaadọta ni Chinyere ti aburo rẹ to jẹ abikẹyin ati ọkunrin kan ṣoṣo tawn obi wọn bi si jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgbọn
Ọmọ mẹrin ni Chinyere bi fun ọkọ rẹ ti ọlọpaa mu ti aburo rẹ si ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo ni oṣu karun ọdun 2021.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkọ ìyàwó tó pa ìyàwò rẹ̀ nítorí ogún tó ní
- Ọ̀rọ̀ yìí gbẹnután!,Ìyá dú ọmọ rẹ̀,o yí láta,ó wá jòkó jẹ ẹ́
- Lát'ojú orun, ikú omi gbígbóná ni Saliu tẹ́rí sí; bí ọwọ́ ṣe tẹ ìyàwó rẹ́ nìyí
- Akẹ́kọ̀ọ́ rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún he lẹ́yìn tó ná $1m tó ṣèèṣì wọ àpò àsùnwọ̀n rẹ̀
- Lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí wọ́n sìnkú rẹ̀, obìnrin yìí di dédé yọ sí ìlú rẹ̀, l'ọ̀rọ̀ bá di...
Ki lo ṣẹlẹ gaan?
Edna Durueke,to jẹ ibatan awọn to padanu ẹmi wọn sọ fun BBC pe iṣẹlẹ yi waye lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta 2022 nigba ti arabainrin Chinyere dari lati Scotland.
O ni ile ti iṣẹlẹ yi ti waye wa ni adugbo Abule Ado ki a to de Trade Fair nilu Eko.
''Alẹ ọjọ to de lati irinajao ni iṣẹlẹ buruku yio waye. O ṣeni laanu pe ko di ọjọ keji''
Arabinrin Dureke sọ pe arabinrin naa ati ọkọ rẹ ti pari ija wn ki o to lọ si Scotland ṣugbọn ko mọ pe ko tan ninu ọkọ rẹ.
O ni awọn pada mọ pe bi obinrin naa ṣe fi orukọ rẹ nikan sori iwe ile ti wọn n gbe gẹgẹ bi ẹni to ni ile naa lo mu inu bi ọkọ rẹ.
"Oṣiṣẹ ile ifowopamọ ni ibatan mi ti o si n ṣe daada ni Naijiria ko to lọ silẹ okere.Ki o to lọ, ile ti wọn n yagbe kan ni wọn wa ni Dopemu.''
''O pada ko owo jọ ti wọn si ra ilẹ ni Abule Ado ti wọn si kọ ile. Lẹyin igba naa, o ri iwe igbelu gba to si lọ kẹkọ gboye ni Scotland. Iwe igbelu yi fun lanfaani lati gbe mọlẹbi lọ. Oun, ọkọ ati ọmọ mẹrin ni wọn jijọ lọ''
Dureke tẹsiwaju pe ''Ko si ẹni to mọ ohun to mu ki ọkọ pada wa si Naijiria.Amọ iyawo pada gbọ wi pe ọk gbiyanju lati ta ile wọn.Ko ribi ta nitori pe orukọ iyawo lo wa lori gbogbo iwe ile''
O ni ọrọ yi lo da wahala silẹ toun lero pe o mu ki ọkọ binu dana sun iyawo rẹ nitori oun ko gbọ nipa ede aiyede miran laarin wọn.
'Oju orun lo ti da epo bẹntiroo siwa lara'
Awọn ọlọpaa ni aburo iyawo sọ ọrọ ikẹyin ko to gbẹmi mi.
Alukoro ọlọpaa Benjamin Hundeyin sọ pe awn ribi gba ọrọ́ lẹnu aburo iyawo ki o to ku.
''Gbogbo nkan ti aburo iyawo yi sọ lo wa ni akọsilẹ.O ni bawọn ṣe pada de, ija waye laarin lọkọ laya tawn si pada lọ sun. Ṣadede lo ni oun gburo nkan to tutu bi omi lara awọn''.
O ni bawọn ṣe yaju lawọn ri pe bẹntiroo lo da si ara awọ. Ki a to wi ka to fọ, o ti sọ ina sawọn lara to si ti lẹkun sa jade ninu iyara.
Alaye ree ti alukoro ọlọpaa ni aburo arabinrin naa ṣe fawọn ko to jade laye.
'Ile iwosan da aburo pada pe awọn ko le tọju rẹ''
Ile iwosan ẹlẹkẹẹta ti wọn gbearakunrin naa lo ku si gẹgẹ bi Edna Durueke ti ṣe sọ.
O ni arakunrin naa kuro ni ile rẹ to wa ni Ajah lati lọ gbe ẹgbọn rẹ nigba to dari lati iluOyinbo.
'' Nigba ti ilẹ ṣu lo sọ pe oun ko ni le pada sile lo ba fi sun si ọdọ wọn''
''Nkan bi ago mẹrin lawọn alabagbe n gboorun eefin.Ko si ẹni to gbọ bi awọn ibatan mi ṣe npariwo ninu ile''

Oríṣun àwòrán, Chinyere Ogudoro
''Awọn araadugbo gbiyanju ti wọn si ribi jalẹkun wọ inu ile wọn. Oku iyawo ni wọn ba ti wn si sare gbe aburo rẹ lọ si ile iwosan ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi.''
''Awọn wọnyi sọ pe awọn ko le tọju iru eṣe bayi tori naa wn dari wọn lọ si LUTH.Bi wọn ṣe de LUTH,awọn naa dari wọn lọ si Gbagada pe nibẹ niwọn ti n tọju ẹni ti ina ba jo lara.''
''Oju ọna Gbagada lo ti dakẹ''
Ki lawọn ọlọpaa n ṣe bayii?
Afurasi ọkọ iyawo yi wa latimọle ọlọpaa lẹka ọtẹlẹmuyẹ, Panti ladugbo Adekunle ni ilu Eko.
Wọn ni bandeeji wa lara ọkọ iyawo to si ni ina jo oun naa lara ṣugbọn oun ribi moribọ.
Amọ ṣa alukoro ọlọpaa Hundeyin sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lati le fi mọ ohun to ṣẹlẹ gaan.
Awọn mọlẹbi ni awọn ọmọ tọkọtaya yi ṣi wa ni Scotland nitori wọn ko mọ nkan to n ṣẹlẹ bayii.





























