Kí ló lè mú kí ìyá pa ọmọ rẹ̀ sè jẹ?

Aworan iya to n dana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn alaṣẹ lorileede Tanzania ti ni ki awọn oṣiṣẹ ijọba agba tẹ ọkọ leti ni kiakia lati lo foju ri oun to n ṣẹlẹ labule kan lẹyin ti iroyin kan pe obinrin kan pa ọmọ rẹ jẹ.

Gẹgẹ bi ohun takọroyin BBC jabọ, wọn ni labule Mavanga ni obinrin naa ti fọbẹ du ọmọ rẹ,to se e ki o to wa bẹrẹ si ni jẹ.

Awọn agbofinro ti mu obinrin naa ati ọkọ rẹ lati fọrọ wa wọn lẹnu wo.

Emmanule Ngalikakwa to jẹ kansilọ agbegbe naa ṣalaye fakọroyin BBC ohun ti obinrin naa sọ fawọn aṣaaju abule.

O ni nigba ti wọn kọkọ beere ọrọ lọwọ obinrin naa, o ni ohun ju oku ọmọ naa si inu ṣalanga ni lẹyin toun pa.

Ni igba ti wọn tẹ ninu daada, o yi ọrọ pada to si sọ pe okuta nla loun fi fọ ọmọ naa lori ki ohun to gbe oku rẹ lọ si inu igbo.

Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ, nigba to de inu igbo to sọ, obinrin naa sọ fun wọn pe ohun du ọmọ naa ki ohun to ge wẹlẹwẹlẹ ti oun si se jẹ.

Ko ti daju boya arun ọpọlọ n damu arabinrin naa ṣugbọn awọn ọlọpaa ni o y ki iwaadi awọn sọ ohun to muhu iriiwa bẹ.