Ekiti Robbery: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ekiti ní òun kò ti i mọ iye èèyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn

Ile ifowopamọ ti adigunjale fọ

Oríṣun àwòrán, @Nationainsight

Àkọlé àwòrán, Ekiti Robbery: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Ekiti ní òun kò ti i mọ iye èèyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ti kede pe isẹlẹ idigunjale miran tun ti waye ni ilu Ọyẹ Ekiti lọsan oni.

Iroyin naa salaye pe ado oloro ni awọn adigunjale naa lo lati fọ ile ifowopamọ ọhun, ti wọn si ko owo tuulu lọ nibẹ.

Koda, gẹgẹ baa se ka lori ẹrọ ayelujara, aaye gba awọn adigunjale ọhun to bẹẹ gẹ, ti wọn tun fi yin ado iku mọ ọkọ ọlọpaa to sẹburu ọna ti ko jẹ ki wọn raye kọja lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ, osisẹ alarena fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ogu Caleb salaye fun BBC Yoruba pe lootọ ni isẹlẹ naa waye ni deede aago meji abọ ọsan.

Ọkọ ọlọpa ti awọn adigunjale dana sun

Oríṣun àwòrán, @Bamisey

Caleb ni ileesẹ ọlọpaa ti n sisẹ takuntakun lati sawari awọn firindiọkẹ to sisẹ laabi naa, ti ẹlẹsẹ wọn ko si ni lọ laijiya pẹlu afikun pe oun ko ti i lee sọ iye eeyan to ba isẹlẹ naa rin.

Isẹlẹ idigunjale yii ni yoo jẹ ikeji laarin osu meji nipinlẹ Ekiti, akọkọ ni eyi to waye lọjọ Kẹrindinlọgbọn, osu Kẹsan an, ọdun ta wa yii nilu Isan Ekiti.

Àkọlé fídíò, Pneumonia: Dókítà ní kòkòrò àìfojúrí ló ń fàá