Ẹni ọdún 27 tó ṣá bàbá rẹ̀ pa l'Ogun dèrò àtìmalé

MAN ARRESTED FOR MATCHETING HIS FATHER TO DEATH

Oríṣun àwòrán, Abimbola Oyeyemi

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ogun ti fi ṣikun ofin mu okunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Sikiru Ibrahim, lori ẹsun pe o ṣa baba rẹ pa.

Wọn mu afurasi naa ni ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2022, lẹyin ti ọgbẹni kan, Abiodun Sunday, fi ọrọ rẹ sun ni ago ọlọpaa Onipanu.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Abimbola Oyeyemi fi ṣọwọ si BBC lo ti fi ọrọ naa lede.

Oyeyemi sọ pe oloogbe ọhun, Mumuni Ibrahim, to jẹ ọlọdẹ oru de lati ibi iṣẹ rẹ, to si ba afurasi naa to n sun.

Lẹyin naa lo bere lọwọ afurasi ọhun to fi n sun ni irufẹ akoko bẹẹ.

Ka to wi, ka to fọ, o ti fa ada yọ, to si ṣa baba rẹ ni igba marun un ọtọtọ.

Ni kete ti iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti ni wọn tẹkọ leti lọ si ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ti wọn si fi ṣikun ofin mu afurasi naa, nigba ti wọn gbe baba rẹ digbadigba lọ sile iwosan fun itọju.

Àkọlé fídíò, Babatunde Adejumo: Ọdún méje ní mi fi sá kúrò nídìí iṣẹ́ aṣerunlọ́sọ̀ọ́ àmọ́ mo padà

Atẹjade naa ni "Afurasi naa, ti igbagbọ wa pe o jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun ko le ṣalaye eredi to ṣe ṣa baba rẹ pa nigba ti a fi ọrọ wa lẹnu wo."

"Nigba to di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2022 yii ni oloogbe naa jade laye lasiko to n gba itọju lọwọ, ti awọn mọlẹbi rẹ si sọ pe awọn gbọdọ sin oku rẹ ni ilana ẹsin rẹ."

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti paṣẹ ki wọn gbe afurasi naa lọ si ẹka ti wọn ti n ṣe iwadii ẹsun ipaniyan ni ẹka CID fun iwadii ni kikun, ko si tun le tete foju bale ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Abdulfatai Balogun: N kò ríran àmọ́ oníṣòwò Yoghurt ní mí tó ń fi àwìn sàánú fún oníbàárà