Àrá sán pa ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin tó ń gbá bọ́ọ̀lù nínú òjò l'Ondo

Lightning kills four young men in Ondo community

Oríṣun àwòrán, Esanradio/tv

Ara ti san pa ọdọkunrin mẹrin lasiko ti ojo n rọ lagbegbe Agọ Dada to wa ni ijọba ibilẹ Ariwa Akure, ni ipinlẹ Ondo.

Awọn oloogbe naa ti iroyin sọ pe wọn kii ṣe ọmọ oniluu n gba bọọlu lasiko naa ki ara to san pa awọn mẹrẹrin.

Irọlẹ Ọjọbọ ni iṣẹlẹ naa waye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmi Odunlami lo fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin.

Ifẹhonuhan bẹrẹ lẹyin iṣẹlẹ ọhun

Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe awọn eeyan awọn oloogbe ọhun, ti wọn kii ṣe ọmọ onilu bẹrẹ ifẹhonuhan lori bi iṣẹlẹ kayeefi naa ṣe waye.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn olufẹhonuhan naa yabo aarin igboro, ti wọn si bẹrẹ si n ba awọn dukia jẹ latari awọn eeyan wọn to ku iku ojiji.

Iroyi ni wọn ba ile ati dukia awọn ọmọ bibi agbegbe naa jẹ lasiko ifẹhonuhan naa.

Àkọlé fídíò, Babatunde Adejumo: Ọdún méje ní mi fi sá kúrò nídìí iṣẹ́ aṣerunlọ́sọ̀ọ́ àmọ́ mo padà

Amọ Odunlami ṣalaye pe ko si ẹmi ẹnikankan to sọnu lasiko ti ifẹhonhan ọhun waye.

O ni "Lootọ ni awọn ọdọ mẹrin padanu ẹmi nigba ti ara san pa wọn ni abule naa."

"Amọ ko si ẹmi ẹnikẹni to sọnu lasiko ti awọn eeyan wọn n ṣe ifẹhonuhan nitori awọn oṣiṣẹ wa lọ sibẹ lati mu ohun gbogbo bọ sipo."

Ẹwẹ, awọn oniṣẹṣe kan ti lọ sibẹ lati ṣe etutu lori iṣẹlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Omi Adio Robbery: Èèyàn márùn-ún tí kò mọwọ́-mẹsẹ̀ ló kú lásìkò ìdigunjalè PoS l‘Omi Adio