Baba Ijesha: Dejo Tunfulu, ọ̀kan lára alátìlẹyìn mi nílé ẹjọ́ ló kú yìí, inú mi bàjẹ́

Baba Ijesha ati Princess

Oríṣun àwòrán, babaijesha/princesscomedian/Instagram

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba to n jẹjọ lori ẹsun ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọde, Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ mọ si Baba Ijesha tun ti yọju sile ẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Nibi igbẹjọ naa to waye ni ile ẹjọ giga to wa ni Ikeja, niluu Eko ni Baba Ijesha ti mu ọkan lara awọn ẹlẹri rẹ wa siwaju adajọ.

Ẹlẹri ọhun, Kayode Ogunbanjo, ti ọpọ eeyan mọ si Pasitọ Jerosi, to jẹ ẹlẹri kẹrin ninu awọn ẹlẹri mẹrin ti afurasi naa fa kalẹ, lo sọ ohun ti oju rẹ ri lori ẹjọ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹlẹri naa, to jẹ ọkan lara awọn to n ba Baba Ijesha ṣiṣẹ papọ, to si jẹ ẹni to mọ nipa ibaṣẹpọ to wa laarin afurasi ọhun ati ẹni to fẹsun kan, iyẹn Princess.

Àkọlé fídíò, 'Láti kékeré mo ti ní ọjọ́ kan lèmi náà ọ́ kọ́ Mọ́sálásí kékeré bíi àwọn bàbá wa'
Àkọlé fídíò, Babatunde Adejumo: Ọdún méje ní mi fi sá kúrò nídìí iṣẹ́ aṣerunlọ́sọ̀ọ́ àmọ́ mo padà

Lootọ ni ọrọ ifẹ wa laarin Baba Ijesha ati Princess, iya Princess gan sọ fun Baba Ijesha loju mi pe ko tọju ọmọ oun:

Jerosi, ẹni to sọ fun ile ẹjọ pe o ti to ọdun mẹẹdogun ti oun ti n ba Baba Ijesha sisẹ, salaye pe lootọ ni ajọsepọ wa laarin Baba Ijesha ati Princess.

O wa fidi rẹ mulẹ pe Princess gan pe Baba Ijesha lasiko ọkan lara eto alawada rẹ to maa n se, eyi to pe ni Orisun.

"Awa marun la maa n se eto naa papọ, lọjọ naa nigba ti eto naa n lọ, Princess pe lori aago pe oun fẹ dara pọ mọ eto naa.

Lọjọ kan lo wa ke si Baba Ijesha pe ko wa si ile rẹ ni Iwaya, emi si ni mo wa mọto lati gbe Baba Ijesha lọ sibẹ.

Nigba ta de ile naa, Baba Ijesha dọbalẹ fun iya Princess, ti obinrin naa si sọ pe "Maa tọju ọmọ mi daadaa."

Asiko yii ni Baba Ijesha sẹsẹ wa sọ fun mi pe oun n fẹ Princess amọ o ti n gbe ibasepọ naa kọja ibi to yẹ."

Amọ nigba ti agbẹjọro fun olupẹjọ, Yusuff Sule n fi ọrọ wa ẹlẹrii naa lẹnu wo, Jerosi ni oun ko mọ ohunkohun nipa isẹlẹ to waye nile Princess lọjọ Kọkandinlogun osu Kẹrin ọdun 2021.

O ni lọjọ naa, Agbegbe Aguda ni Surulere ni oun wa, ti oun ko si mọ isẹlẹ to waye nile Princess.

Nigba to ba BBC Yoruba sọrọ, ọkan lara awọn agbẹjọro Baba Ijesha, ọmọọba Kayode Olabiran, SAN, sọ pe ni bayii ti awọn ti mu gbogbo awọn ẹlẹri awọn wa sile ẹjọ, ohun to kan ni ki awọn ba ile ẹjọ sọrọ lori akojọpọ awijare awọn, iyẹn 'written address."

Olabiran ni oun gbagbọ pe onibara oun yoo ri idajọ ododo gba lori ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí

Ki ni Baba Ijesha ba BBC sọ lori iku Dejo Tunfulu:

Nigba ti Baba Ijesha naa n ba BBC Yoruba sọrọ lẹyin igbẹjọ naa, o ni inu oun ko dun rara nitori iroyin iku akẹgbẹ oun pataki to jade laye, iyẹn, Dejo Tunfulu.

Baba Ijesha ni Dejo jẹ ọkan lara awọn to duro ti oun lati igba ti ẹjọ naa ti bẹrẹ.

O ni "Inu mi ko dun rara, iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni."

"Ọrẹ mi ni, akẹgbẹ mi ni, ẹgbọn mi si ni pẹlu, iku rẹ ko dun mọ mi ninu rara."

"Ṣe bi ẹyin naa ri nile ẹjọ yii nigba ti wọn parọ mọ wa."

Baba Ijesha pari ọrọ rẹ pe ko si ẹni ti ko ni ku, nitori naa ki gbogbo mutu-muwa maa ṣe daadaa nitori ọjọ atisun.

Ẹwẹ, wọn ti sun ẹjọ naa si ọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ti a wa yii.

Àkọlé fídíò, Sanni Iyabo Paramount Komedy: Ibi tí mo ti rí àwọn ọfọ̀ apanilẹ́rìín tí mò ń lò nínú 'skit