Kwara Rituals: Tẹ̀gbọ́n tàbúrò wọ gbaga ọlọ́pàá fẹ́sùn híhú òkú bàbá wọn fún ògùn owó

Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, NPF

Àkọlé àwòrán, Ọlọ́pàá

Ilé ẹjọ́ Májísíréètì kan tó fi ìlú Ilorin, olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara ṣe ibùjókòó, ti ní kí tẹ̀gbọ́n tàbúrò, Abdullateef àti Yusuf Adekanye lọ máa ṣe fàájì ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ìgbà kan .

Ẹ̀sùn híhú òkú bàbá wọn láti fi ṣe ètùtù ọlà àti lílẹ̀dí àpò pọ̀ láti hùwà yìí ni wọ́n fi kàn wọ́n.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ní Ọjọ́rú, ọgbọ̀njọ́, oṣù Kẹta, ọdún 2022 wọ́ àwọn ọkùnrin méjéètì lọ síwájú ilé ẹjọ́ láti wí tẹnu wọn lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn ẹ̀sùn náà gẹ́gẹ́ bí olùpẹjọ́ ṣe wí lòdì sí òfin orílẹ̀ èdè yìí, tó sì ní ìjìyà lábẹ́ òfin.

Àkọlé fídíò, Abdulfatai Balogun: N kò ríran àmọ́ oníṣòwò Yoghurt ní mí tó ń fi àwìn sàánú fún oníbàárà

Báwo ni ọwọ́ ṣe tẹ̀ wọ́n?

Ẹni tó pe ẹjọ́ náà, Moshood Adebayo ni Abdullateef àti Yusuf kó àwọn ènìyàn kan wá sí agbolé wọn láti hú òkú bàbá wọn, Zakarya Adekanye láì sọ fún mọ̀lẹ́bí kankan.

Adebayo ní àwọn afurasi afinisetutuọla náà hú òkú bàbá wọn tó wà ní Agba Akin ní ìlú Offa, níbi tí wọ́n sin bàbá náà sí láti ọdún 2012.

Ó ní àwọn afurasí ọ̀hún hú òkú náà, tí wọ́n sì kó gbogbo egungun rẹ̀ lọ láti lọ fi ṣe ògùn owó léyìí tó lòdì sí òfin ilẹ̀ wa.

Bákan náà ló rọ ilé ẹjọ́ láti fi àwọn afurasí náà sí àhámọ́ títí tí ẹjọ́ náà yóò fi ní ojútùú.

Ṣùgbọ́n àwọn afurasí náà ní àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn.

Adájọ́ fi àwọn afurasí sí àhámọ́

Adájọ́ Mohammed Adams wá ní kí àwọn afurasí náà wà ní àhámọ́ fún ìgbà kan na.

Bákan náà ló sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Kejìlá, oṣù kẹrin, ọdún 2022.

Àkọlé fídíò, Funke-Gbenga Adetuberu: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run rèé tó ní ọmọ líle, ó sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí