Lukuluku Bantashi: Aláwàdà tí yóò kun èédú sójú, wọ aṣọ ìyá kò bá bàbá tan, ìdúró rẹ̀ lásán pa ní lẹ́rìn-ín

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ òde òní, ó ṣeéṣe kí wọ́n má mọ̀ nípa Lukuluku Bantashi.
Sùgbọ́n gbogbo àwọn tó bá ti tó ojú bọ́ láàárín ọdún 1980 sí ọdún 1990, gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú tí orúkọ rẹ̀ kò le parẹ́ ni Lukuluku Bantashi.
Gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú tó lórúkọ lágbolé tíátà, tó sì lo ìgbà tiẹ ní Lukuluku Bantashi ń ṣe nítorí ó ní àmì ìdánimọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò tii lé bá títí di àsìkò yìí.
Fún gbogbo àwọn tó bá wo eré sinimá Yemi My Lover, Ti Oluwa Nilẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, máa gbà wí pé láì sí gbajúgbajà adẹ́rìnínpòṣónú Lukuluku Bantashi nínú àwọn eré láyé ìgbà náà, eré náà kò le tà.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wèrè ọlọ́mọ ní Dejo Tunfulu, ọmọ mẹ́rin ní ìyá wa dà sílẹ̀ fún, tó sì bá ọkọ míì lọ - Ọmọ olóògbé
- Wo gbajúmọ̀ aláwàdà Yorùbá méjọ tó ti kú saájú Dejo Tunfulu
- Baba Ijesha ń fẹ́ Princess, ìyá Princess gan sọ lójú mi pé kó tọ́jú ọmọ òun dáadáa - Ẹlẹ́rìí Kẹrin
- Àlàyé rèé lórí aìsàn tó pa Dejo Tunfulu àti ilé ìwòsàn tó dákẹ́ sí
- Ikú Dejo Tunfulu ti kó ìrẹ̀wẹ̀sí ọkàn bá mi, ń kò le kópa nínú eré tà ń yà mọ́ - Ọ̀gá Bello
- Mo ti gba ìdúnkookò ikú tórí mo tako ṣíṣí bodè Lekki padà - Mr Macaroni
- Irọ́ ní Atiku, Saraki, Tambuwal àtàwọn yókù ń pa pé àwọn ọ̀dọ́ ló dá N40m owó fọ́ọ́mù ìdíje sípò ààrẹ fún àwọn - Obasanjo
- "Àwọ̀ ara àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jóná nínú bọ́ọ́sì ń ṣí mọ́ wa lọ́wọ́ nígbà tà ń dóòlà ẹ̀mí wọn"
- N kò rí oorun sùn lórí iṣẹ́ ibi àwọn agbésùnmọ̀mí, òògùn oorun gan kò ràn mí - El-Rufai
- "Táyà tírélà tó ta pàù lójijì lo fọ mi loju, di mi leti, o tun ge apa èmi àti ọmọ mi"
Ọ̀kan lára àwọn òṣèré tí ikú kò jẹ́ kí ènìyàn gbádùn obì wọn tó gbó ní Lukuluku Bantashi .
Awo Erin, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe máa ń pè é, ni ikú ja gbà mọ awọn ololufẹ rẹ lọwọ lásìkò tí àwọn ènìyàn ń gbádùn rẹ̀ jùlọ.
A kò mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan nípa ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ lẹ́yìn agbo tiata ṣùgbọ́n tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ká ṣe àwàdà, òdú ni Lukuluku Bantashi, tí kìí ṣe àìmọ̀ fún olóko lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn ilẹ́ Nàìjíríà.
Lukuluku Bantashi gẹ́gẹ́ bí aláwàdà:
Nígbà tí Lukuluku Bantashi ń ṣe àwàdà lágbolé tíátà, gbogbo àwọn Baba Suwe, Ajirebi, Godogbo, James Dẹpẹ, Dejo Tunfulu, Larondo àti àwọn mìíràn máa ń tò lẹ́yìn rẹ̀ ni.
Lásìkò yìí, gbogbo àwọn olóòtú eré sinimá ló máa ń fẹ́ kí ó wà nínú àwọn sinimá àwọn nítorí àwòràn rẹ̀ lásán lára pálí ìpolówó, máa ń jẹ́ kí eré bẹ́ẹ̀ tà wàràwàrà.
Bí ó ṣe máa ń gbé ẹnu ẹkún rẹ̀ jẹ́ ohun kan pàtàkì tó yà á sọ́tọ̀ nínú àwọn eléré àti àwọn adẹ́rìnínpòṣónú tí wọ́n jọ lògbà nigba naa.
Àgbàlagbà tí yóò kun èédú sójú, tí yóò wọ aṣọ ìyá kò bá bàbá tan, ni Lukuluku sábà máa ń ṣe nínú eré.
Ìdúró rẹ̀ lásán le mú ènìyàn máa rẹ́rìn-ín àríntọ̀sára.

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Bí Lukuluku Bantashi ṣe jáde láyé:
Ilẹ̀ mì tìtì ní gbogbo ẹkùn gúúsù ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà ní ọjọ́ tí wọ́n kéde ikú Lukuluku Bantashi lọ́dún 1995.
Gbogbo ilé iṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣàn ló mọ̀ wí pé akọni lọ lọ́jọ́ tí à ń wí yìí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣèré tíátà ló gbà lọ́jọ́ náà wí pé ká tó rérin ó digbó, ká tó rẹ́fọ̀n, ó dọ̀dàn, ká tó rí irú Lukuluku Bantashi lágbolé tíátà, ó di gbéré.
Gbogbo ènìyàn ló kọrin arò lẹ́yìn akọni tó lọ bi o tilẹ jẹ pe aisan ranpẹ lo se, to fi jade laye, ko si sẹni to fura pe ọlọjọ lo de.
Nígbà tó ń gbìyànú láti gbé ọkàn àwọn ènìyàn kúrò lórí Lukuluku Bantashi, gbajúgbajà agbóhùnsáfẹ́fẹ́, Alhaji Gboyega Lawal sọ nínú ètò rẹ̀ kan wí pé Lukuluku jí ǹ de.
Alhaji Lawal múra fún Yinka Ayefele láti dàbí Lukuluku Bantashi láti gbe wà sórí ètò ONROSY, tí ó sì mú kí àwọn ènìyàn pọ̀ níbi ètò náà.
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ nígbà àwọn ènìyàn mọ̀ wí pé Lukuluku kọ́ ló wà lábẹ́ aṣọ.
Ó ti pé ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n báyìí tí Lukuluku Bantashi ti fi ayé sílẹ̀ àmọ́ ipò rẹ̀ kò tán lọ́kàn àwọn tó mọ̀ ọ́ nígbà ayé rẹ̀.



















