Esabod and Lizzy Anjorin: Àwọn ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Esther Aboderin Esabod

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Lati bi ọjọ diẹ ni ori ayelujara ti n daru laarin oṣerebinrin Lizzy Anjorin ati agbohunsafẹfẹ ori ayelujara, Esther Tokunbo Aboderin, Esabod.
Ọrẹ ni ọpọ mọ awọn mejeeji si botilẹ jẹ pe Esabod ju Lizzy lọ lọjọ ori to bẹẹ ti Lizzy funrarẹ sọ ninu fidio kan pe oun maa n bọwọ fun Esabod.
Ọrẹ awọn mejeeji di ilumọọka lasiko ija to waye laarin Toyin Abraham ati Lizzy Anjorin
Ṣùgbọ́n bayii, ojojumọ ni àwọn mejeeji n sọ ọrọ ti ko dara nípa ara wọn.
Taa ni Esther Tokunbo Aboderin, Esabod?
Ọmọ bibi ilu Ibadan ni Esther Tokunbo Aboderin, ti awọn ololufẹ rẹ tun mọ si Esabod.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 1961 ni wọn bi sinu gbajugbaja ẹbi Aboderin n'ilu Ibadan.
O lọ si ile ẹ̀kọ́ girama n'ilu Ibadan. Bakan naa lo wọ Fasiti ilu Ibadan, lati kawe nipa imọ iṣegun oyinbo. Sugbọn iroyin sọ pe ko pari ẹ̀kọ́ rẹ.
Esabod fẹ ọkọ rẹ akọkọ lọdun 1982. Ọmọkùnrin kan ati obinrin lo bi fun ọkọ rẹ, ko to di pe igbeyawo naa tuka.
Lẹyin naa lo fi orile-ede Naijiria silẹ, to si fi United Kingdom ṣe ibugbe.
Nigba to de United Kingdom, o fẹ ọkọ miran, Niyi Oyewole, ti ọpọ mọ si Gadaffi.
Ọmọ meji ni wọn bi fúnra wọn, eyi to sọ ọmọ Esabod di mẹrin.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, awakọ ni Niyi Gadaffi jẹ fun Esabod nigba to wa ni Naijiria.
Igbeyawo naa tuka, nitori bi Niyi ṣe ma n lu Arabinrin Esabod to si n hu iwa ipa si àwọn ọmọ naa.
A gbọ pe ìjọba orile-ede Ireland tu wọn ka, to si pasẹ fun Niyi lati rin jina si i.
Ọdun 2010 lo bẹrẹ si ni ṣe eto lori ayelujara Facebook, nibi to ti ma n tu aṣiri àwọn iyawo ile to jẹ ọmọ Naijiria, to n yan àlè, paapaa awọn to n gbe ni oke okun.
Bakan naa, o to akoko to bẹrẹ si ni kẹnu bọ ọrọ awọn gbajumọ oloṣelu Naijria to fi mọ awọ gbajugbaja oṣere ni Naijiria lẹyin ti wọn ti ṣaaju rii bi olulaja ti wọn bọwọ fun.
Bákan naa lo ma n tu awọn asiri ikọkọ nipa awọn osere tiata Yoruba.
Eto naa lo sọ ọ di gbajumọ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo fẹ́ràn rẹ, àwọn kan ko gba tiẹ.
Eyi seese ko jẹ nitori awọn ọrọ alufansa, èpè ati awọn ọrọ miran ti eeyan n sọ ni ikọkọ, sugbọn ti Esabod kii tiju lati sọ sita ni gbangba toun ti ina siga rẹ ti yoo maa tu lẹnu.
Yatọ si pe Arabinrin Esabod jẹ oniṣowo, o tun n ṣe iṣẹ́ tewe-tegbo, nibi to ti ma n ta orisirisi agbo ati agunmu loke okun ati lawọn orilẹede mii.
Ẹnu kii sì lara Esabod Aboderin
Ọ̀pọ̀ igba ni iroyin ti jade nipa Esabod, paapaa nitori iru iroyin to ma n gbe jáde lawọn oju opo rẹ ati bo ṣe maa n fesi si awọn iroyin nipa rẹ.
Lara àwọn gbajumọ to ti jẹ 'ẹgba' lori eto ati iroyin ti Esabod n gbe jade ni Wasiu Ayinde, Bola Tinubu, ati ọpọlọpọ osere Yoruba, ti ko ni onka.


















